ETO ẸKỌ IGBALODE JẸ IJỌBA IPINLẸ OGUN L’OGUN GIDI – SALAKỌ-OYEDELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 8, 2020

ETO ẸKỌ IGBALODE JẸ IJỌBA IPINLẸ OGUN L’OGUN GIDI – SALAKỌ-OYEDELE

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti fi da gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa l’oju wi pe eto ẹkọ igbalode lo jẹ ijọba wọn l’ogun, to si l’ojoojumọ l’awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe eto ẹkọ ipinlẹ naa ba ti igbalode agbaye mu.

Salakọ-Oyedele lo f’idi ọrọ naa mulẹ lasiko to n gba ẹgbẹ awọn akẹkọọjade ti ẹka ikẹkọọ imọ-ẹrọ (Faculty of Engineering Alumni Association) ni fasiiti ilu Eko, UNILAG l’alejo laipẹ yii n’ilu Abẹokuta.

Nibẹ lo si ti sọ pe gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa ni yoo jẹ ninu anfaani eto ẹkọ tuntun yii lai ni i fi igba kan bo ọkan ninu

O ni eyii lo mu k’awọn bẹrẹ si i tun gbogbo awọn ile ẹkọ ti wọn ti fẹ ẹ d’ẹnu kọlẹ tan kaakiri ipinlẹ ṣe, nitori pe agbegbe to ba dun un wo lo le mu k’oriya wa f’awọn akẹkọọ at’awọn olukọni.

Bẹẹ lo tun sọ pe awọn ti wa lori igbesẹ lati ri i pe awọn olukọni naa bẹrẹ si i gb’adun, nitori pe inu olukọni ti ko ba dun ko le jẹ ko ṣe awọn nnkan to tọ l’asiko.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI