EYII NI BÍ AHMED LAWAN ÀTI BUKỌLA SARAKI ṢE PÀDÉ NI PATI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, February 16, 2020

EYII NI BÍ AHMED LAWAN ÀTI BUKỌLA SARAKI ṢE PÀDÉ NI PATI


Ẹ̀kọ́ ńlá gba a lọ yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà máa jẹ f'áwọn ọdọ, pàápàá àwọn ọdọ tí wọn fẹran láti máa lu ara wọn nítorí àwọn olóṣèlú yìí. Ohun tó dájú ni pé tẹtẹ l'awọn olóṣèlú Nàìjíríà ń fi àwọn aráàlú tá, èyí t'ọpọ àwọn èèyàn ro pe wọn ń jà lóòótọ́.

Aarẹ ilé igbimọ aṣofin àgbà lorilẹ-ede yìí, Sẹnetọ Ahmed Lawan lo pàdé Ààrẹ àná, Sẹnetọ Bukọla Saraki ni òde àríyá kan n'ipinlẹ Akwa-Ibom. 

Ibi ìsìnkú bàbà Gomina Udom Emmanuel t'ipinlẹ náà, ìyẹn Olóògbé Alagba Gabriel Emmanuel Nkanang l'awọn méjèèjì tí pàdé, tí wọn sì di mọ ara wọn. 

Kò dá, tí wọn tún jọ sọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ kò too di pé ayẹyẹ náà wá s'opin. Ọ̀pọ̀ àwọn tó rí wọn bí wọn ṣe ń ṣe ló ń yà lẹ́nu wí pé lóòótọ́ ni kò sí ọ̀tá ayérayé nìdí òṣèlú Nàìjíríà.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI