ORUKA NI OLUWO FI GBA MI - ỌBA ỌGBAAGBA TI OLUWO DA ẸṢẸ BO SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 17, 2020

ORUKA NI OLUWO FI GBA MI - ỌBA ỌGBAAGBA TI OLUWO DA ẸṢẸ BO SỌRỌ

Ọba Sikirulahi Akinrọpo, Agbowu t'ilu Ọgbaagba ti Oluwo t'ilu Iwo, Ọba Abdulrọṣheed Akanbi lu l'ọsẹ to kọja yii, eyi to da awuyewuye nla s'ilẹ kaakiri igboro ti sọrọ, o si sọ awọn nnkan to ni Oluwo fi gba oun l'ẹṣẹ.

Agbowu t'ilu Ọgbaagba ni oruka ti Oluwo wọ s'ọwọ rẹ lo fi gba oun l'ẹṣẹ l'oju to mu ki oju oun ge ati pe diẹ lo ku ki oju oun fọ danu l'asiko ti Ọba naa sọ oun di baagi ẹṣẹ (punching bag).

Ninu ọrọ Ọba Akinrọpo lo tun ti ṣalaye kulẹkulẹ bi ọrọ naa ṣe jẹ. Eyii l'awọn nnkan to sọ:

"Kii ṣe ipade l'asan la lọ ọ ṣe, ipade alaafia ti igbakeji ọga ọlọpaa n'ilu Oṣogbo pe la lọ fun. Kii ṣe akọkọ iru ipade bayii re e, igbakeji ọga ọlọpaa to wa n'ilu Oṣogbo tẹlẹ, iyẹn Lẹyẹ Oyebade ti kọkọ pe wa, to si l'ọro jagidijagan níkan l'oun le da si, ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, o rọ wa pe ka lọ ọ yanju ọrọ to ba ku ni Aafin Oluwo.

"Ẹsun ti Oluwo fi kan emi at'awọn ọba kan ni pe a n ta ilẹ ẹ, ṣugbọn ti a sọ fun un (Oluwo) pe ilẹ wa la n ta, ki i ṣe ilẹ ti ẹ. N'igba ti a ri i pe eto aabo aafin le jẹ ipalara fun wa, la fi lọ ọ ṣe ipade naa ni gbọngan oloye to wa ni ileeṣẹ ijọba ibilẹ Iwo, ti a si pe awọn eleto aabo sibẹ.

"Ko pẹ ti a jokoo ni Oluwo funra rẹ de pẹlu awọn onilu at'awọn tọọgi ẹ, awọn ọlọpaa sọo fun Oluwo pe ko le ko awọn tọọgi naa wọle, ṣugbọn wọn fi agidi wọle sibẹ, ko pẹ la gba ẹyinkule jade. Awa ọba ti ko din ni ọgbọn n'ijọba ibilẹ Iwo, Ọlaoluwa ati Ayedire la wa n'ibẹ.
"Bi a ṣe kuro n'ibẹ ni igbakeji ọga ọlọpaa naa de, igba ti ko ri wa lo jẹ k'oun naa pada. Ori igbiyanju lati tun ipade alaafia naa pe lo wa ti wọn fi gbe e kuro, ti wọn si gbe ẹlomi-in wa. N'igba ti Makama de, oun naa gbiyanju lati pe ipade alaafia yii, to si kọ lẹta si wa pe ka yọju s'oun.

"Oluwo sọ pe oun ko le gba ka maa ta ilẹ l'awọ agbegbe t'oun ti jẹ olori, tori pe oun ni olori gbogbo ọba to wa labẹ Iwo. A si jẹ ko ye e pe ilẹ ti a n ta ki i ṣe ti Oluwo, bi ko ṣe awọn ilẹ to wa n'igberiko wa.

"Olu t'ilu Ile-Igbo sọ pe ilẹ agbegbe ẹ l'oun n ta, bẹẹ naa ni Onigẹgẹ naa sọ, t'emi at'awọn yooku naa si sọ bẹẹ. Alaga ijọba ibilẹ Iwo lo jokoo laarin emi ati Oluwo. Kọmisanna fọrọ oye jijẹ at'ijọba ibilẹ, amofin, aṣoju kọmiṣanna f'ọrọ ilẹ at'awọn mi-in ni wọn lori ijokoo.

"Kọmiṣanna fọrọ oye jijẹ at'ijọba ibilẹ sọ pe ka lọ sile ẹjọ, ati pe oun yoo fi ọrọ naa to gomina leti. Ṣadede ni mo ri Oluwo to dide mọ mi, to si bẹrẹ si i ko ẹṣẹ bo mi loju, awọn to wa nibẹ gbiyanju lati gba mi lọwọ ẹ, ṣugbọn ko gba, afigba ti igbakeji ọga ọlọpaa dide lati gba mi silẹ. N'igba to maa dide, oju mi ti ge, oruka ati kọkọrọ mọto to wa l'ọwọ ẹ lo ya mi loju.

"A ko le yanju ipade naa, tori pe Oluwo ti da gbogbo ẹ ru, to si jẹ pẹntuka n'ipade naa yọri si i. O ti ẹ tun gbiyanju lati lu mi lẹẹkeji, ṣugbọn igbakeji ọga ọlọpaa yiii lo sọ pe k'awọn ọmọṣẹ ẹ gbe e jade. Irọ lo pa wi pe mo bu oun, ati pe mi o pe e lorukọ buruku."

Idi ti mi o ṣe ba Oluwo ja pada

"Ọdun kẹrinlelogun re e ti mo ti wa n'ipo ọba, mo si mọ iyi ati nnkan ti ipo naa duro fun un. Ko ṣẹlẹri wi pe ki ọba maa yọ ẹṣẹ tabi ko maa ja. Mi o le si nídi iwa were, idi ni yii ti mo fi wa ni alaafia. Ti mo ba gbiyanju lati ba a ja pada, emi naa yoo di were n'iyẹn."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI