CORONAVIRUS: ÀWỌN TÓ LÉ NÍ 143 NI WỌ́N TI KÓ PAMỌ́ NÍ NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 2, 2020

CORONAVIRUS: ÀWỌN TÓ LÉ NÍ 143 NI WỌ́N TI KÓ PAMỌ́ NÍ NÀÌJÍRÍÀ


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, kò dín ni ọgọrun kan àti mẹtalelogoji {143} èèyàn káàkiri orilẹ-èdè Nàìjíríà là gbọ pé wọn tí fura fura si wí pé ó ṣe é ṣe kí wọn ní aarun aṣekupani, Coronavirus.

Ìpínlẹ̀ Ogun, Eko ati Plateau là gbọ pé wọn tí kò àwọn èèyàn náà pamọ láti lè dẹ́kun itankalẹ aarun náà. 

Kọmiṣanna f'eto ìlera n'ipinlẹ Plateau, Dọkita Nimkong Ndam f'idi rẹ múlẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú tí í ṣe Sande wí pé àwọn mẹtalelogoji {43} l'awọn tí kò pamọ síbi tí wọn yà sọtọ f'awọn tó bá ní aarun náà tí wọn tún pe ni COVID-19. 

Ìjọba ìbílẹ̀ Wase tó wà n'ipinlẹ Plateau lo sọ pé àwọn èèyàn náà wá, tó sì jẹ kò di mimọ pé àwọn èèyàn náà ni wọn ní ajọṣepọ pẹ̀lú àwọn ọmọ orilẹ-èdè China mẹ́rin tí wọn wá láti ìlú Addis Ababa

Dọkita Ndam sọ pé ọjọ́ mẹrinla gbáko làwọn èèyàn náà yóò lo níbi t'awọn kò wọn pamọ sì láti wo ó bóyá aarun náà yóò jẹyọ lára wọn kò tó o di pé àwọn tún mọ igbesẹ tó bá kan. 

O ni àwọn ọmọ orilẹ-èdè China mẹta ni wọn wọ Nàìjíríà láàárín ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí, ó ní àkọ́kọ́ lo de lọ́jọ́ Aje tí í ṣe Mọnde, nígbà táwọn méjì yòókù de lọ́jọ́ Wẹside, gẹgẹ bí wọn ṣe fi tó Gomina Lalong létí. 

Bákan náà, àwọn tí kò dín ni ọgọrun n'ijọba ipinlẹ Eko ati Ogun tí kò pamọ báyìí lórí aarun aṣekupani, Coronavirus náà láti wo bí ara wọn yóò ṣe ṣe sí láàárín ọjọ́ perete.

Kọmiṣanna feto ìlera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lọ fìdí ẹ múlẹ̀ wí pé àwọn èèyàn náà làwọn tí ṣe ìwádìí, táwọn sì rí í pé àwọn ni wọn laṣẹpọ pẹ̀lú ọkùnrin ẹni ọdún mẹrinlelogoji tó ko Coronavirus wọ Nàìjíríà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI