EEMỌ! WỌN LU MỌNSURU IJAYEGBEMI, GBAJUMỌ OṢERE TIATA NI JIBITI ẸGBẸRUN MARUN-UN NAIRA, LO BA FẸẸ GBE MAJELE JẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 15, 2020

EEMỌ! WỌN LU MỌNSURU IJAYEGBEMI, GBAJUMỌ OṢERE TIATA NI JIBITI ẸGBẸRUN MARUN-UN NAIRA, LO BA FẸẸ GBE MAJELE JẸ

Bi ki i ba a ṣe ori to ko gbajumọ oṣere tiata nni, Ọgbẹni Mọnsuru Ijayegbemi yọ lọwọ iku ojiji ni, boya aye ko ba ma ti mọ-ọn lonii, nitori pe diẹ lo ku ko gbe majele jẹ lori bi ẹni kan ṣe luu ni jibiti ẹgbẹrun marun-un naira.

Mọnsuru Ijayegbemi to saba maa n ṣe ‘oloye’ ninu sinima lo tu aṣiri naa funra rẹ lori redio kan niluu Abẹokuta lonii, ọjọ Aiku ti i ṣe Sannde.

Eto kan to gbajumọ daadaa, ti wọn pe ni ORIYỌMI, eyi ti gbajugbaja olorin nni, Yinka Ayefẹlẹ maa n ṣe lori redio rẹ n’ilu Abẹokuta ni ọkunrin naa ti sọrọ, to si l’oun ko le gbagbe ọjọ naa titi aye.

Ijayegbemi to f’ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ṣe ibugbe n’igba to n sọrọ sọ pe oun dupẹ gidigidi l’ọwọ Ọlọrun nitori pe Ọlọrun lo orin Oloogbe Fatai Olowonyọ lati ra ẹmi oun pada n’igba naa, nitori pe oun ko ba ti di ẹni igbagbe.

Ninu ọrọ Ijayegbemi, o sọ pe “Mo dupẹ pe ori yọ mi, ẹri si kan mi. L’ọdun 1985 ni ẹnikan lu mi ni jibiti ẹgbẹrun marun-un naira. Owo naa pọ gidi n’igba naa. Ironu yii lo mu mi ra majele, ti mo si daa sinu tii (tea) lati fi gba ẹmi ara mi.

“Orin kan lo nmi igboro titi n'igba naa, orin Fatai Olowonyọ to sọ pe 'Ki lo ṣe ẹ to n ronu, ẹni to ṣubu lonii ṣi maa dide'. Orin yii ni mo gbọ n'igba naa ti mo tun fi ronu pada, tori pe ṣe lo dabi iwaasu fun mi, o si mu ori mi wu gidi.


"Ibẹ ni mo wa ti ọkan lara awọn ọrẹ mi ti kan ilẹkun, mo wa a sare palẹmọ, mo si nu omije oju mi danu. Bi ọrẹ mi ṣe wọle, lo sọ pe mo n gbadun. Ṣe lo gbe tii (tea) ti mo ti da majele si, eyi ti mo fẹẹ gbe mu, ki n si ku danu, to si fẹ ẹ mu.


"Ṣe ni mo sare gba a danu lọwọ ẹ pe ko gbọdọ muu. Inu bii gidi gan wi pe mi o jẹ k'oun mu ninu tii (tea) ti mo n gbadun, o binu gan-an, mo si bẹẹ pe ko ma binu. Mo ṣẹṣẹ wa a ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ fun un


"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe gbogbo ẹ ti d'ohun igbagbe bayii, ti mi o si pa ara mi n'igba yẹn. Ọpọlọpọ nnkan rere ni mo ti ṣe lonii, ẹri kan mi, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI