ẸGBẸ̀RÚN MẸ́RÌNDÍLỌ́GỌ́TA L'AWỌN TO TÍ FORÚKỌ SÍLẸ̀ FÚN IṢẸ́ ÀGBẸ̀ L'ÓGÚN - ỌDẸ́DÍNA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, March 16, 2020

ẸGBẸ̀RÚN MẸ́RÌNDÍLỌ́GỌ́TA L'AWỌN TO TÍ FORÚKỌ SÍLẸ̀ FÚN IṢẸ́ ÀGBẸ̀ L'ÓGÚN - ỌDẸ́DÍNA

Kọmiṣanna feto iṣẹ àgbẹ̀ nipinlẹ Ogun, Ọmọwe Samson Adeọla Ọdẹdina tí fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé kò dín ni ẹgbẹ̀rún mẹrindinlọgọta làwọn èèyàn tó ti forúkọ silẹ fún iṣẹ agbẹ àti ọgbin nipinlẹ náà láàárín asiko perete tí wọn gbé fọọmu síta. 

Ọjọ́ Aje, ìyẹn Mọnde àná ni Ọmọwe Ọdẹdina sọrọ náà létí gbogbo agbaye níbi eto ifọwọsowọpọ pẹ̀lú ìjọba ipinlẹ Eko láti ṣagbatẹro ata, ìyẹn Tomato, èyí tó wáyé n'ilu Abẹ́òkúta.

Kọmiṣanna sọ pé yàtọ̀ sí pé yatọ si pe awọn ẹgbẹrun mẹrinlọgọta ti wọn ti forukọ silẹ yii, ojoojumọ l'awọn eeyan tun ṣi n forukọ silẹ fun eto agbẹ, to si ti n din airiṣẹ ṣe awọn ọdọ asiko yii ku.

Image may contain: 3 people, people standing 
O ni anfaani yi ti faaye silẹ fun eto agbẹ igbalode, ti yoo si tun ṣi oju ọpọ awọn eeyan s'awọn afaani to wa lagbegbe wọn.

N'igba to n sọrọ, Kọmiṣanna eto agbẹ ati alajẹṣẹku n'ipinlẹ Eko, Ọmọba Gbọlahan Lawal sọ pe eto ajọṣepọ naa yoo mu idagbasoke eto agbẹ, ati pe yoo f'awọn ọlọja lanfaani lati gbe ọja wọn de ibi to yẹ.

O jẹ ko di mimọ pe ilẹ to ku l'Ekoo ko le pese ounjẹ f'awọn araalu, paapaa bo ṣe jẹ ilu omi n'ilu Eko, to si lo o jẹ pataki idi t'awọn fi pawọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ogun. 

N'igba to n gba ẹnu gomina ipinlẹ Ogun sọrọ, igbakeji Gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele sọ pe ọna lati jẹ ki ajọṣepọ laarin awọn ileeṣẹ aladani ati t'ijọba, eyi ti wọn pe ni Public Private Partnership (PPP) dan mọnran lo jẹ k'awọn pinnu eto naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI