O PARI! 'KINNI' GBE JẸLILI LỌ ṢẸWỌN GBERE L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, March 14, 2020

O PARI! 'KINNI' GBE JẸLILI LỌ ṢẸWỌN GBERE L'ABẸOKUTA

Orin 'a o pade leti odo' l'awọn eeyan n kọ fun Kazeem Abdul-Jẹlili ti wọn lo o fipa b'ọmọdun mẹsan an laṣepọ ninu kilaasi n'igba t'ile-ẹjọ paṣẹ wi pe ko lọ lo eyi toku n'igbesi aye rẹ l'ọgba ẹwọn.

l'Ọjọbọ, iyẹn Tọside to kọja yii n'ile-ẹjọ giga to wa lagbegbe Iṣabọ, Abẹokuta ju Jẹlili, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa s'ẹwọn gbere.

Ẹsun ifipabanilopọ ni wọn fi kan Jẹlili, ọmọdun mẹsan-an lo si f'ipa ja ibale rẹ, iyẹn l'ọdun 2011.

Ile-ẹkọ kan to wa l'agbegbe Abiọla-Way, Abẹokuta ni Jẹlili ti n kọ awọn akẹkọọ ni imọ ẹkọ bi wọn ṣe n ya nnkan (fine Art), asiko ti wọn l'awọn akẹkọọ ti lọ sile la gbọ pe Jẹlili ki ọmọ naa mọlẹ ninu kilaasi, to si ja ibale rẹ.
 
A gbọ pe ṣe ni ọmọ naa ṣalaye ọrọ yii fun ọkọ mama rẹ (step-father), to si gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ko to o di pe awọn ọlọpaa gbe e.

Ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye, Abẹokuta ni wọn ti fidi rẹ mulẹ wi pe loootọ ni wọn ti fa idi ọmọ naa ya pẹrẹpẹrẹ, eyii gan lo jẹ k'awọn ọlọpaa f'oju rẹ ba ile-ẹjọ.

N'igba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidajọ Patricia Oduniyi sọ pe gbogbo ẹri to wa niwaju oun lo f'idi mulẹ pe loootọ ni Jẹlili huwa naa, to si gbọdọ jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin, to si paṣẹ wi pe ko lọ lo eyi toku igbesi aye rẹ l'ọgba ẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI