OPIN AYE! BỌSẸ ṢALAYE B'AWỌN PASITỌ ṢE N LO O FUN AYEDERU IṢẸ IYANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 14, 2020

OPIN AYE! BỌSẸ ṢALAYE B'AWỌN PASITỌ ṢE N LO O FUN AYEDERU IṢẸ IYANU

O ti ṣe diẹ bayii ti ọwọ ọlọpaa ti tẹ gbajumọ obinrin ọmọ bibi ilu Ileṣa, n'ipinlẹ Ọṣun, iyẹn Bọsẹ Ọlasunkanmi, ẹni t'ọpọ awọn Pasitọ maa n lo fun ayederu iṣẹ iyanu kaakiri orilẹ-ede Naijiria.

Iyaale ile naa to l'ọmọ mẹta l'oun bi ki ọkọ oun to o ku sọrọ yii fun oniroyin kan n'ilu Eko, iyẹn ni teṣan ọlọpaa to ti n gbatẹgun lọwọ bayii, nibẹ lo si ti sọ pe oun ṣetan lati mu awọn ọlọpaa de gbogbo ṣọọṣi ti wọn ti l'oun fun ayederu iṣẹ iyanu naa.

Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji yii sọ pe o ti pẹ t'oun ti padanu ọwọ ati ẹsẹ oun s'inu ijamba mọto, bẹẹ lo tun fidi rẹ mulẹ wi pe musulumi pọmbele l'oun, ṣugbọn atijẹ lo sun oun debi jibiti yii, ki i ṣe ẹjọ oun rara.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ile--ẹkọ alakọbẹrẹ ti Nawair-ud-deen ni mo lọ, ti mo si ṣetan lọdun 1988. Ọdun 1989 ni mo de ilu Eko pẹlu iya mi, ko to o ku l'ọdun 1990. Lẹyin ti mama mi ku, mo lọ n ba wọn ta ounjẹ, ti mo si lo ọdun mẹsan-an gbako nibẹ.

Ọdun 1999 ni mo n'ijamba mọto, nibẹ ni mo si ti padanu ọwọ ati ẹsẹ mi ọtun. Ẹni ti mo n ba taja n'igba naa le mi danu wi pe mi o le b'oun ṣiṣẹ mọ. Eyi lo jẹ ki n lọ s'ile ẹgbọn mi to wa n'Igando, ọdun 2000 si 2003 ni mo fi wa l'ọdọ ẹgbọn mi yẹn, ibẹ ni mo si ti pade ọkọ mi ti mo bimọ meji fun.

Ọdun 20017 ni ọkọ mi ku, ko si si oluranlọwọ kankan latigba náà, kò sì ibi tí mo fẹ́ ẹ gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, ìdí re e tí mo fi kò àwọn ọmọ mi lọ sọ́dọ̀ anti mi, inú ṣọọbu là ń sún sì í.

Ṣọọbu náà ni mo ti pàdé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ Fatila Musa, mo tọrọ owó lọ́wọ́ ẹ, ó sì fún mi lẹgbẹrun kan {1000} náírà. Nígbà tó rí ọwọ mi, ó lòun yóò mú lọ sáwọn ṣọọṣi kan tí máa tí máa rí owó gidi.

Ọdún 2018 lo tún padà wá, torí pé mi ò rí í látìgbà náà, ó sì mú mi lọ sí ṣọọṣi kan ni Ọgbà, l'Ekoo. Radiant Army Deliverance Ministry lórúkọ ṣọọṣi náà, Pasitọ Tony Anthony lo nii.

Ká tó o de bẹ, Fatila tí kọ mi làwọn nnkan ti mo máa ṣe, ó ti sọ bí mo ṣe máa gbé ọwọ mi sókè, a sì ti ṣe idanrawo nílé dáadáa ká tó o lọ.

Bí mo ṣe de ṣọọṣi náà, Pasitọ yìí tí mọ nnkan tó fẹ́ ẹ ṣe, torí pé Fatila tí fi fọto mi ranṣẹ sì i, èmi kò mọ, ṣe ló fi aṣọ sínú inura sì mi lọ́wọ́, ó ti fi òróró sì í, ó ní ṣe mọ gbagbọ wí pé ọwọ mi máa padà sípò, mo sì ní bẹẹni. Bó ṣe ṣetan ni mo bẹ̀rẹ̀ si í gbé ọwọ náà díẹ̀ díẹ̀.

Ẹgbẹ̀rún mẹsan án náírà ni Fatila fún mi nígbà tí a ṣetan. Ọjọ́ kẹta lo tún mu mi padà lọ sí ṣọọṣi náà, Pasitọ Anthony pé mi síta, ó sì sọ níwájú gbogbo èèyàn wí pé òun yóò fi miliọnu kan náírà rán mi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò fún mi lowo kankan. Ká ní mo gbà owó náà ni, mi o tún ní padà sí ṣọọṣi kankan mọ.

Oṣù Kẹjọ ọdún 2019 tó padà wa lo tún mú mi lọ sí ṣọọṣi mi-in ni Port-Harcourt, ọdọ Pasitọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo mú mi lọ. Pasitọ kan ṣe iṣẹ́ ìyánu tiẹ láàrin ọjà. Ibẹ là tún gbà de ilu Abakaliki.


Ṣọọṣi kan tí wọn ń pè ní Mountain of Liberation and Miracle Ministry to wa ni Ojodu-Berger lo tún mú mi lọ, ibẹ sì ni ṣọọṣi tí mo lọ gbẹyin, Pasitọ Chris Ọkafọr lo ni i.

Bi mo ṣe jókòó lo dárúkọ mi, tí mo sì jáde sí í. Mí ó rí Pasitọ yìí rí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Fatila sọ gbogbo bí mo ṣe jẹ́ fún un. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lo fún mi nígbà tí a kúrò nibẹ.

Kò pẹ ni Fatila pé mi wí pé ẹnikan tó ń jẹ Henry fẹẹ fún mi ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó {400,000} náírà. Ìgbà tí mo pé ẹni náà, lóòótọ́ lo fún mi lowo náà.

Ṣe ló dabi ẹni pé Henry tí mọ irú èèyàn ti mo jẹ, ṣe ló sọ pé kí n má bá wọn ṣe ayédèrú iṣẹ ìyanu mọ lailai. Ó ní kí n lọ fi owó náà gbà ṣọọbu àti ilé tí máa máa gbé.

Ṣọọbu tí mo fi owó náà gba lágbègbè Igando làwọn ọlọ́pàá tí wá a mú mi. 

Mo kabamọ pupọ pé mo ṣe iṣẹ́ yìí, àwọn ọmọ mi kò mọ pe nnkan ti mo ń ṣe nìyẹn. Ká ní mo mọ pe fọ́nrán mi yóò jáde sórí ayélujára ni, mi ò bá má tí tẹsiwaju. Ìṣẹ́ lo sún mi de bẹ, torí pé opo ni mí. Ṣé làwọn ọmọ mi bù sẹkun nígbà tí wọn gbọ.

Mo ṣetan láti mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí gbogbo ṣọọṣi tí wọn tí lo mi fún ayédèrú iṣẹ ìyanu. Abamọ ńlá lo jẹ́ fún mi, àwọn Pasitọ náà gbọ́dọ̀ jìyà ẹṣẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI