YAHYA BELLO BU SẸKUN NITORI IKU MAMA RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 16, 2020

YAHYA BELLO BU SẸKUN NITORI IKU MAMA RẸ


Ko ṣeni tó rí Gomina Yahya Bello t'ipinlẹ Kogi lọ́jọ́ Aiku Sannde àná níbi tó ti ń sunkún bí ọmọdé lórí ikú màmá rẹ, tí kò ní fẹ́ ẹ bá a sunkún pẹ̀lú.

Gomina Yahya Bello lo pàdánù màmá rẹ, Hajia Hawa Bello ni ọsibitu kan tó wà nílùú Abuja lẹ́yìn àìsàn rampẹ tí wọn lo ó dà á dubulẹ láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn.


A gbọ pé bí wọn ṣe tufọ ikú Hajia Hawau fún Gomina Bello ni kò lè muu mọ́ra, tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ bù sẹkun níwájú àwọn èèyàn. 

Òní ọjọ́ Aje, Mọnde ni wọn yóò sìnkú màmá náà silu Okẹnẹ tó wà nipinlẹ Kogi ni ìlànà musulumi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI