ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ SỌ̀RỌ̀ L'ORI ILEEṢẸ ÌJỌBA 'TREASURY HOUSE' TO JÓNÀ L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 8, 2020

ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ SỌ̀RỌ̀ L'ORI ILEEṢẸ ÌJỌBA 'TREASURY HOUSE' TO JÓNÀ L'ABUJA


Ní nǹkan bí aago kan ọsan òní ni ariwo náà gbà gbogbo orilẹ-èdè Nàìjíríà pé ẹ̀ka ileeṣẹ ìjọba tí wọn ti ń rí sì eto iṣuna, ìyẹn Treasury House jóná.


Ìyàlẹ́nu ni bí ẹ̀ka ileeṣẹ náà ṣe jóná lásìkò konilegbele yìí ṣe jóná, nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni, nítorí pé gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba pátápátá ní wọn wá ní igbele tipátipá láti dẹkùn itankalẹ aarun Koronafairọs.


Bi ìròyìn náà ṣe jáde síta wí pé ileeṣẹ tó jẹ́ pé ọga àgbà oluṣiro eto iṣuna owó orílẹ-èdè yìí tí jóná làwọn ọmọ Nàìjíríà tí gba orí ìkànnì ayélujára lọ láti lọọ kọ ọ síbẹ̀ pé ejò lọ́wọ́ nínú. 


Wọn ní bí ileeṣẹ iṣuna owó náà tí wá lágbègbè Garki, Abuja ṣe jóná kí í ṣojú lásán, àti pé ó lọ́wọ́ àwọn àgbà olóṣèlú orílẹ-èdè yìí nínú.

Titi di asiko tá a kọ ìròyìn yìí tán ni ìjọba orílẹ-èdè yìí kò ti í sọ ohunkóhun lórí ile tó jóná náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI