AYÉ GBẸGẸ O! WỌN BÁ ORÚKỌ ÀWỌN ÀGBÀ OLÓṢÈLÚ NÀÌJÍRÍÀ NIGBALẸ BABALÁWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 8, 2020

AYÉ GBẸGẸ O! WỌN BÁ ORÚKỌ ÀWỌN ÀGBÀ OLÓṢÈLÚ NÀÌJÍRÍÀ NIGBALẸ BABALÁWO


Ṣé lọrọ di womi-n-wo-ẹ lọ́jọ́ Tuside àná nígbà tí ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Zamfara ya wọ igbalẹ awon babalawo to wa lagbegbe Unguwar Dallatu nilu Gusau, ìpínlẹ̀ náà, tí wọn sì bá orúkọ àwọn àgbà olóṣèlú nibẹ.

Àwọn ará agbegbe naa là gbọ pé wọn tá ileeṣẹ ọlọpaa lolobo nípa àwọn afurasi ọmọ ẹlẹgbẹ òkùnkùn tí wọn fi agbegbe naa ṣé ibùgbé.

Ọga ọlọpaa ìpínlẹ̀ náà, Usman Nagogo lọ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fáwọn oniroyin, tó sì lẹsẹkẹsẹ táwọn tí gbọ làwọn tí dìde lọ síbẹ̀. 

O ni bàwọn èèyàn náà ṣe gburo pé àwọn ọlọpaa tí wá láyìíká wọn ní wón ti na pápá bora, kò dá, to ni ṣe ni wọn pòórá mọ àwọn lójú.

Nagogo ni bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò rí ẹnì kankan mú nínú wọn, ṣùgbọ́n tó ní oríṣiríṣi ohun ìbẹ̀rù lo kún inú ilé wọn náà, èyí tó làwọn rí nnkan bí ìgbà tó kún fún ẹ̀jẹ̀, orí òkú gbígbẹ, aṣọ àti ìwé tí wọn kọ orúkọ àwọn àgbà olóṣèlú sì. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI