Ẹ TÚN WÒ B'ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ ṢE YẸYẸ BUHARI NÍTORÍ ỌJỌ́ MẸRINLA TÓ FI KÚN KONILEGBELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 14, 2020

Ẹ TÚN WÒ B'ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ ṢE YẸYẸ BUHARI NÍTORÍ ỌJỌ́ MẸRINLA TÓ FI KÚN KONILEGBELE


Irọlẹ àná Mọnde ni Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà, Muhammadu Buhari tún báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹẹkeji fún tí àrùn aṣekupani kogboogun, ìyẹn COVID-19 tí wọn tún ń pè ní Koronafairọs, nibẹ lo sì tún ti kede wí pé konilegbele tòun pàṣẹ rẹ lọsẹ méjì sẹ́yìn ṣí ń tẹsiwaju.

Ààrẹ Muhammadu Buhari to sórí káàkiri ileeṣẹ redio àti tẹlifiṣan, tó fi mọ àwọn ìkànnì ayélujára mélòó kan bí í fesibuuku. 

Ogunlọgọ àwọn ọmọ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé ni wọn tẹti gbọ ọrọ Ààrẹ Buhari tó sọ, nibi to tí dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn èèyàn fún aduroti wọn, pàápàá bí wọn ṣe tẹle àwọn òfin àti ìlànà.

Ààrẹ ni gẹgẹ bí ṣe jẹ́ pé ibo làwọn ọmọ Nàìjíríà fi gbé òun àtàwọn adari wọlé sípò, gbogbo adojukọ àti ìyá táwọn èèyàn ń jẹ ye òun yekeyeke, tó sì ni fún ìgbà díẹ̀ ni. 

O ni ki í ṣe pé ìjọba mọ-ọn-mọ láti fìyà jẹ àwọn aráàlú bí kò ṣe pé ọ̀nà kan ṣoṣo táwọn le fi dẹkùn itankalẹ àrùn Koronafairọs nìyẹn, àti pé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá-ńlá bí í Italy, China, US náà ni wọn ti ilẹkun mọra wọn báyìí.
 
Bí Ààrẹ Buhari tí ṣòro yìí làwọn ọmọ Nàìjíríà tí inú ń bí ti bẹ̀rẹ̀ si í dá a lóhùn lórí ìkànnì ayélujára wí pé kò fẹ́ràn aráàlú, nítorí pé kò mẹnuba àwọn iranlọwọ tijọba ni fáwọn aráàlú, pàápàá àwọn tó kú díẹ̀ kaato fún.

Díẹ̀ re e lára àwọn nǹkan táwọn èèyàn sọ sì Ààrẹ Buhari:







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI