Bí kí í bá a ṣe pé orí tó ko ọmọdébìnrin tí ẹ n wo yìí yọ ni, ó ṣeé ṣe kí àwọn ajinigbe pá a dànù, tàbí kí wọn tí lo ó fún nnkan ètùtù.
Ọmọdébìnrin náà ti wọn pé orúkọ rẹ ni Ọpẹyẹmi Ogunlẹyẹ tí wọn l'ọmọdun méjìlá ni là gbọ́ pé ìlú Ogere, ipinlẹ Ogun lo tí kúrò wá a tà pọfupọọfu n'ilu Abẹ́òkúta.
Lẹ́yìn tí wọn lo tí tà pọfupọọfu náà tán lo gbìyànjú láti wọ mọto lọ sí àgbègbè Sango-Ọta, níbi tí wọn làwọn òbí rẹ ń gbé.
Ibi tó ti ń gbìyànjú láti tọrọ owó kún owó ọwọ ẹ ní wọn sọ pé obìnrin kan tí dá a dúró, tó sì fẹẹ gba gbogbo owó ọwọ ẹ, kò sì tún gbé e salọ, ìyẹn lágbègbè Kutọ.
Asiko yii gan án ní wọn làwọn òṣìṣẹ́ fijilante, ìyẹn VGN ń ṣiṣẹ kọjá lọ, tí wọn sì fura si nnkan tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọmọdébìnrin yìí àti obìnrin náà.
Wọn ní báwọn fijilante ṣe rí nnkan tó ń lọ yìí ni wọn ti sáré lọ síbẹ̀ láti túbọ̀ mọ nnkan tó ń ṣẹlẹ̀ síwájú sí í, ìyàlẹ́nu ni wọn lo o jẹ pe obìnrin náà tí na pápá bora ki wọn tó o debẹ.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà f'AWIKONKO, Kọmanda Nureni Ọlanrewaju Adedoyin sọ pé lóòótọ́ ni, ati pe lẹsẹkẹsẹ tí ìròyìn náà tí tẹ òun lọ́wọ́ lòun tí pàṣẹ wí pé kí wọn lọọ fà á lé àwọn ọlọpaa Ibara lọ́wọ́.
Kọmanda Adedoyin lo jẹ́ kó ye wá pé iṣẹ ọmọọdọ ni wọn ń fi Ọpẹyẹmi n'ilu Ogere tó wà tẹle, tó sì jẹ pe ilokulo ni wọn ń lo ó nibẹ, ìdí re tó ní ọmọ náà fi pinu láti salọ sọdọ àwọn òbí tó ń gbé ní Sango.
O wa a jẹ kò di mimọ pé kani kii ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ tí gba idanilẹkọọ dáadáa ní, ó ṣeé ṣe kí àṣírí àwọn afurasi ajinigbe náà má tú sí wọn lọ́wọ́, kí wọn sì ti lọọ pá ọmọ náà dànù.
Ó wà fi dá àwọn ọmọ ipinlẹ Ogun àti agbegbe rẹ lójú wí pé kí wọn fọkanbalẹ, kí wọn sì má ṣe bẹ̀rù mọ nítorí pé asiko táwọn wá yìí, àsìkò táwọn tí wọ ìyá ìjà pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn ni, ati pe ko saaye fún ìwà ọ̀daràn kankan mọ.
Bẹẹ lo tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé pẹ̀lú ajọṣepọ tó wà láàrin àwọn àti ileeṣẹ ọlọpaa, tó fi mọ àwọn ileeṣẹ eleto tó kú káàkiri, àwọn yóò rí pé ìwà ọ̀daràn dohun ìgbàgbé nipinlẹ Ogun pátápátá, tí àlàáfíà yóò sì jọba.
No comments:
Post a Comment