KORONAFAIRỌỌSI! ẸGBẸ̀RÚN MẸ́FÀ ARÁÀLÚ TÚN JẸ ÀǸFÀÀNÍ OWÓ ÀTI IRANWỌ KÓNÍLÉGBÉLÉ NÍ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 30, 2020

KORONAFAIRỌỌSI! ẸGBẸ̀RÚN MẸ́FÀ ARÁÀLÚ TÚN JẸ ÀǸFÀÀNÍ OWÓ ÀTI IRANWỌ KÓNÍLÉGBÉLÉ NÍ KWARA


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú ìdùnnú àti ayọ̀ làwọn ará ìjọba ibilẹ Oke-Ero, ipinlẹ Kwara wá lórí owó àti oúnjẹ iranlọwọ t'ijọba fún wọn lori konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.

Ọjọ́ Wẹside àná làwọn aráàlú tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún mẹ́fà je àǹfààní ńlá yìí. Igbimọ t'ijọba yàn láti ṣabojuto eto naa là gbọ pé ogún miliọnu {20,000,000} náírà ni wọn kò lọ sáwọn wọọdu mẹ́wàá tó wà n'ijọba ibilẹ Oke-Ero. 


Lára àwọn tó jẹ́ àǹfààní yìí làwọn arúgbó, òpó, alaabọ ara, oniṣẹ ọwọ àtàwọn tó kú díẹ̀ kaato fún lai fi ojúsàájú ṣe.

Lónìí yìí, ìjọba ibilẹ mẹẹdogun nínú mẹrindinlogun lo tí jẹ àǹfààní yìí, lára wọn sì ni Ilọrin West, Ilọrin South, Ilọrin East, Aṣa, Ifẹlodun, Ọffa àti Oyun. 


Àwọn yòókù ni Patigi, Edu, Kaiama, Baruten, Isin, Irẹpọdun ati Oke-Ero, tá a sì gbọ pé ìjọba ibilẹ Moro nìkan ni wọn ń retí àwọn nǹkan iranwọ wọn báyìí, ṣùgbọ́n t'ijọba yóò debẹ laipẹ. 

Báwọn agbegbe kan ṣe gba oríṣiríṣi oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ làwọn kan gbà owó. 

Gbogbo ọba alaye káàkiri àwọn àgbègbè wọ̀nyí, pàápàá Alọfa t'ilu Ilọfa tó fi mọ àwọn iyalọja ni wọn dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Gomina AbdulRazaq lórí ọ̀nà tí wọn gbé eto naa gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI