ỌGA BELLO TU ÀWỌN ÀṢÍRÍ TẸNIKẸNI KÒ GBỌ́ RÍ, PÀÁPÀÁ NÍPA ÀWỌN ỌMỌ RẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 28, 2020

ỌGA BELLO TU ÀWỌN ÀṢÍRÍ TẸNIKẸNI KÒ GBỌ́ RÍ, PÀÁPÀÁ NÍPA ÀWỌN ỌMỌ RẸ̀


À gbà oṣere tíátà Adebayo Salami, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si ọga Bello, tí sọ ìhà tó kọ sí bí àwọn ọmọ bibi inú rẹ, se ń ba se ere tíátà. Ọga Bello, lásìkò to ń kopa lórí eto kan pẹlu BBC Yoruba ni ọsan ọjọ́ Iṣẹgun, sísọ lójú rẹ pé,
Ọlọ́run ló kọ ọ pé àwọn ọmọ òun yóò ṣe ère orí itage jẹun nitori pe, fúnra wọn ní wọn finnu-findọ pinnu láti máa ṣíṣẹ ère orí itage, òun sì kó lọ kàn-án nípa fún wọn.
O ni: "mo máa ń rí àwọn ọmọ mi bíi osere akẹẹgbẹ mi lásìkò tí a bá ń ṣíṣẹ sinima lọ́wọ́, gbogbo ohun tí wọn ba si ṣe fún mi lásìkò náà, kii dùn mi rárá.
"Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà, tí èmi ati Femi jọ kopa ninu ere, tó si ṣe ọga fún mi, tó ń sọ̀rọ̀ si mi, lẹ́yìn ta parí ère tán, lo padà wá bẹ mi, pé kí n má bínú àmọ́ èyí kò ní ìtumọ̀ kankan sí mi."
Ọga Bello, lásìkò to ń koro ojú sì bí àwọn ère itage ni èdè Yorùbá kan ṣe ń kùn fún ọpọ èdè gẹ̀ẹ́sì, ó ní, èyí dá lórí irú ipò tí èèyàn kan bá fẹ́ ṣe nínú eré.


A mọ́ ó tún woye pe, ìwọ̀nba ni èdè gẹ̀ẹ́sì gbọdọ mọ nínú eré Yoruba.Ọga Bello tún woye pe, nínú sinima ti orin bá ti ń bo ere mọlẹ, a jẹ pé Olootu ere náà kii ṣe akọsẹ-mọṣẹ osere tíátà ni.
Agba ọjẹ nínú isẹ tíátà náà tún ṣiṣọ lójú rẹ pé, olóògbé Ojo Ladipo, ti ọpọ èèyàn mọ si bàbá Mero, ní ọga to kọ òun ni iṣẹ tíátà, òun si lo sọ òun ni inagijẹ Ọga Bello nínú eré tíátà, láti ọdún 1973.
Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI