Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara tí gba gbogbo ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jákèjádò lamọran wí pé kí wọn ṣ'adua lọ́nà tí kò ní í tan àrùn aṣekupani koronafairọọsi káàkiri.
AbdulRazaq lo sọ̀rọ̀ yìí l'Ọjọbọ, Tọside to kọjá yìí lásìkò tó ń báwọn Mùsùlùmí ṣajọyọ aawẹ àti àdúrà ọlọdọọdun wọn, ìyẹn Ramadaani tó bẹ̀rẹ̀ laipẹ yìí.
Gomina AbdulRazaq ni ó ṣe dandan láti gbàdúrà dee de, pàápàá lásìkò aawẹ Ramadaani to wọlé yìí, ṣùgbọ́n tó ní o ṣeni láàánú wí pé àsìkò tí àrùn kogboogun tí COVID-19 ń dá agbaye láàmú ni aawẹ náà bọ sì.
Ìdí re e to fi ní káwọn èèyàn ló àǹfààní konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí láti ṣ'adua lọ́nà tí kò ní í fà itankalẹ àrùn COVID-19, ìyẹn koronafairọọsi náà.
Nínú atẹjade tí Gómìnà fi síta láti ọwọ Rafiu Ajakaye tó jẹ́ akọwe Gomina lo tí sọ pé "Mo bá gbogbo Mùsùlùmí yọ fún tí aawẹ Ramadaani tuntun tó wọlé yìí, oṣù tí Ọlọ́run ń fi àánú rẹ dárí jì gbogbo èèyàn.
"Mo fẹ́ ẹ fi imọriri hàn wí pé asiko yii ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ̀dá pẹ̀lú bí konilegbele ṣe wá káàkiri láti dẹ́kun itankalẹ àrùn COVID-19 fún àǹfààní gbogbo èèyàn.
"Ẹ jẹ ká ṣ'adua Sahuur àti Iftar lọ́nà tí kò ní í tán àrùn tí yóò kó wá sínú ewu, ká sì gbàdúrà sí Ọlọ́run Allah wí pé kò fi ojú àánú rẹ kò wá yọ kúrò nínú ìpọ́njú àrùn bí COVID-19."
No comments:
Post a Comment