ÀṢÍRÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ TRACE TÓ Ń FIPÁ GBÀ OWÓ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ARÁÀLÚ TU, NÍ ỌGA WỌN BÁ FIBINU SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 7, 2020

ÀṢÍRÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ TRACE TÓ Ń FIPÁ GBÀ OWÓ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ARÁÀLÚ TU, NÍ ỌGA WỌN BÁ FIBINU SỌRỌ


Ọga àgbà fún àjọ ẹṣọ ojú popona n'ipinlẹ Ogun, ìyẹn Traffic Compliance and Enforcement CORP {TRACE}, Kọmanda Fatai Owoṣeni Ogunyẹmi tí sọ pé èyíkéyìí nínú òṣìṣẹ́ wọn t'ọwọ palaba rẹ bá ti segi níbi tó ti ń gba owó aitọ yóò fi ẹnu rẹ fẹra bí abẹbẹ. 

AWÍKONKO gbọ pé látìgbà t'ijọba apapọ tí pàṣẹ wí pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò n'ipinlẹ tó wà lọ sí ipinlẹ mi-in làwọn agbofinro tí jáde láti fi òfin náà mulẹ, ṣùgbọ́n tó tún ń jẹ ìyàlẹ́nu wí pé lára àwọn agbofinro yìí ni wọn tún ń gba owó aitọ lọ́wọ́ àwọn èèyàn láti fún wọn láàyè, kí wọn lé kọjá.

Eyii lo mú káwọn tí wọn rí bí nnkan ṣe ń lọ tá àwọn ọga àgbà lolobo, láti fi tó wọn létí nípa ìwà táwọn òṣìṣẹ́ wọn ń hù káàkiri. 

Lónìí ní Kọmanda Ogunyẹmi sọ̀rọ̀ náà jáde nínú atẹjade tí alukoro àjọ náà, Babatunde Akinbiyì fi síta.

Nibẹ lo tí jẹ kò di mímọ wí pé etí òun ti fẹ́ ẹ kún akunfaya lórí ẹ̀sùn tí wọn fi ń kan àwọn òṣìṣẹ́ TRACE káàkiri ipinlẹ Ogun lórí bí wọn ṣe ń lo àǹfààní isede tó wà níta yìí láti gba owó lọ́wọ́ àwọn aráàlú, pàápàá àwọn awakọ.

Owoṣeni Ogunyẹmi sọ pé ó ṣeni láàánú wí pé àwọn tó yẹ kí wọn gbé òfin ro ni wọn ń fọwọ́ pá idà òfin lójú, tó sì ni èyíkéyìí tí àṣírí rẹ bá ti tú ni yóò fi ojú winná òfin ìjọba. 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, o sọ pe "Etí ileeṣẹ yìí tí kún pẹ̀lú bí wọn ṣe fẹsun kan àwọn kan wí pé wọn ń gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́nà aitọ, láti lè jẹ ki wọn raaye kọjá sí Ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè kejì, èyí tó lòdì sí òfin konilegbele tó wà níta láti dẹkun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19. 

"Ikilọ yìí tí fi ẹsẹ múlẹ̀ fún gbogbo àwọn tí aje ọ̀rọ̀ náà bá ṣì mọ lórí, kí wọn sì lọọ tètè jawọ nítorí pé ìjọba tí ṣetan láti bẹ̀rẹ̀ idajọ wọn."

Bẹẹ lo gba àwọn aráàlú lamọran wí pé kí wọn dẹkun láti máa fún àwọn òṣìṣẹ́ TRACE lowo aitọ, yàtọ̀ sáwọn owó tó bá yẹ kí wọn san, àti pé àpò owó ìjọba nìkan ni wọn lé san owó sì, ìyẹn làwọn banki tí wọn ń lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI