AYẸYẸ ỌDÚN KẸWÀÁ! Ẹ GBỌ́ NNKAN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ NÍPA ỌBA ỌLỌ́FÀ T'ILU Ọ̀FÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 9, 2020

AYẸYẸ ỌDÚN KẸWÀÁ! Ẹ GBỌ́ NNKAN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ NÍPA ỌBA ỌLỌ́FÀ T'ILU Ọ̀FÀ


Ko si ẹni tó gbọ nípa ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara sọ nípa Ọlọ́fà t'ilu Ọ̀fà, Ọba Mufutau Gbadamọsi, Eṣuwoye kinni-in tí kò ní í mọ pe lára àwọn Ọba tí wọn ń fi ṣàpèjúwe ọba rere ní.

Oni tí í ọjọ́ Satide, ìyẹn Abamẹta ni ayẹyẹ ọdún kẹwàá tí Ọba Gbadamọsi de ori ipò gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́fà t'ilu Ọ̀fà, to sì jẹ pe gbogbo àwọn ọmọ ìlú náà káàkiri àgbáyé ni wọn ń fi ikú atẹjiṣẹ ikiini ranṣẹ loriṣiriṣi láti bá Kabiyesi ṣajọyọ. 

Gómìnà AbdulRazaq nínú atẹjade tí akọwe ìròyìn rẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye lo tí sọ pé Ọba táwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa wò awokọṣe rẹ fi hùwà ni Ọba Gbadamọsi.

O ni Ọba Eṣuwoye kí í ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni, to sì ti mú idagbasoke alailẹgbẹ bá ìlú Ọ̀fà látìgbà tó ti gba adé àti ọ̀pá àṣẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI