Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́ BÍ ÀṢÍRÍ FRAIDE TÓ P'AWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ FASITI MẸTA ṢE TU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 2, 2020

Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́ BÍ ÀṢÍRÍ FRAIDE TÓ P'AWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ FASITI MẸTA ṢE TU


Ko sẹni to rí bí Friday Akpan àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ ṣe sìnkú àwọn mẹ́ta kan tí wọn jẹ akẹ́kọ̀ọ́ fasiti ipinlẹ Port Harcourt, UNIPORT laipẹ yìí tí àánú abiyamọ kò ní í ṣe é. 

Ọjọ́ keje oṣù kẹrin tí a lo tán yìí là gbọ pé Friday àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ jì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọn pé orúkọ wọn ní Joy Adoki, Nelson Nwafor àti Fortune Obimba gbé. 


Lẹ́yìn tí wọn jì wọn gbé là gbó pé inú igbó ńlá kan ní wọn kò wọn lọ, nibe sì ni wọn ti pá gbogbo wọn dànù. A gbọ́ pé ṣe ni wọn fipá bá èyí tó jẹ́ obìnrin, Joy lasepo kò to ó di pé wọn pá a dànù. 

AWÍKONKO gbọ pé ẹnikan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Bright lo wá nídìí bí wọn ṣe jí àwọn èèyàn náà gbé, lórí ẹ̀sùn tó fi kan wọn wí pé wọn lu òun ni jìbìtì owó. 


Agbegbe kan tí wọn pé ní Etoo n'ijọba ìbílẹ̀ Eleme, ipinlẹ náà là gbọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí wáyé. 

Lẹ́yìn tí a gbọ pé wọn kò rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà làwọn èèyàn wọn lọ ọ f'ọrọ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí, táwọn yẹn sì ṣiṣẹ ìwádìí fínnífínní, kò tó o di pé àṣírí Friday tú sí wọn lọ́wọ́. 


Friday lo mú àwọn ọlọ́pàá lọ sínú igbó tí wọn sìn àwọn èèyàn náà sì í, tó sì ṣeni láàánú pé wọn tí jẹrà kọjá idanimọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI