GBENGA DANIEL BANÚJẸ́ L'ÓRÍ IKÚ AYỌ̀ GÍWÁ, AKỌ̀WÉ ÌRÒYÌN RẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 11, 2020

GBENGA DANIEL BANÚJẸ́ L'ÓRÍ IKÚ AYỌ̀ GÍWÁ, AKỌ̀WÉ ÌRÒYÌN RẸ̀


Gbogbo àwọn akọrọyin n'ipinlẹ Ogun l'ọrọ ikú Ọgbẹni Ayọ Giwa tó ti fìgbà kan rí jẹ́ akọ̀wé ìròyìn fún ìjọba Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí n'ipinlẹ naa, Ọtunba Gbenga Daniel ṣí ń yà lẹ́nu títí di àsìkò yìí. 

Ọtunba Gbenga Daniel gangan lo gbé ìròyìn náà síta lásìkò tó ń banujẹ lórí ikú Ayọ Giwa náà tó di olóògbé ni alẹ́ àná, ìyẹn ọjọ́ Àìkú, Sande. 

Àìsàn rampẹ ni wọn ní Ayọ Giwa ṣe, tó fi di pé ọlọjọ de.

Nínú Ọtunba Daniel lo tí sọ pé "Mo gbà ìpè ijaya nípa ikú èèyàn wa, Ayọ Giwa ni alẹ àná lẹ́yìn àìsàn rampẹ. Ayọ Giwa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Gateway Front Media láti ọdún 2001."

"Lẹ́yìn ìdìbò ọdún 2003, ó di akọwe ìròyìn fún abẹnugọn ilé igbimọ aṣofin ìgbà náà, Ọnọrebu Titi Oseni-Gomez.

"Lẹ́yìn èyí ló di akọwe ìròyìn mi lọ́dún 2011, tó sì jẹ pe ipò náà lo di mú títí tó fi papoda ni alẹ àná. 

"Èèyàn réré tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ tí sẹ́yìn pẹ̀lú bo ṣe gbajumọ iṣẹ rẹ tọkàntọkàn pẹ̀lú ìtẹríba àti ìwà irẹlẹ."

Bákan náà lo tún sọ pé ó ṣeni láàánú wí pé asiko yii ni olóògbé náà lọ, tó sì tún gbàdúrà wí pé Ọlọ́run yóò tú àwọn ẹbí rẹ nínú lórí àdánù ńlá náà. 



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI