NǸKAN DÉ O! GBAJUMỌ EMIR TUNTUN TÚN KÙ NÍ KANO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 2, 2020

NǸKAN DÉ O! GBAJUMỌ EMIR TUNTUN TÚN KÙ NÍ KANO


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí lọ́wọ́, inú ọfọ ńlá làwọn aráàlú Rano tó wà n'ipinlẹ Kano wá, lórí bí Ọba wọn tuntun Tafida Abubakar Illa, ìyẹn Emir t'ilu Rano ṣe waja. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Emir náà tí dàgbà, ẹni ọdún marundinlọgọrin {75} ni, síbẹ̀ kayeefi ńlá ni ikú rẹ ń jẹ fáwọn èèyàn.

F'awọn tó bá mọ bí nnkan ṣe ń lọ ní Kano lásìkò yìí, kí wọn a mọ pe inú ibẹrubojo làwọn aráàlú wa lori bí àwọn èèyàn ṣe ń fò ṣanlẹ kú, tí kò sì ti í sẹni tó lè sọ pàtó ikú tó ń pá wọn. 

Akọwe ìlú Rano, Sank Haruna lo fi ìròyìn náà síta wí pé òun gba ìpè láti ààfin wí pé Emir náà tí kú, ìyẹn ni nnkan bí aago márùn-ún kú ìṣẹ́jú díẹ̀. 

AWÍKONKO gbọ pé àná ni wọn gbé Emir náà lọ sí ọsibitu olukọni, ìyẹn Mallam Aminu Kano Teaching Hospital fun àìsàn kan tí wọn kò lè fìdí rẹ múlẹ̀. 

Nígbà táwọn dọkita l'ọsibitu náà rí i pé agbára wọn kò fẹẹ ká àìsàn náà mọ lo mú kí wọn gbé e lọ sí ọsibitu mi-in fún itọju, nibẹ sì lo dakẹ sì lónìí Satide, Abamẹta. 

Ọkàn lára àwọn Ọba tí Gomina Abdullahi Ganduje ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé adé lè lórí ni Rano tó dá silẹ ni Olóògbé ńaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI