ỌMỌỌBA SAMCO, ÀGBÀ ONÍRÒYÌN ÀTI SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ LO Ń ṢAYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ RẸ̀ LÓNÌÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 15, 2020

ỌMỌỌBA SAMCO, ÀGBÀ ONÍRÒYÌN ÀTI SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ LO Ń ṢAYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ RẸ̀ LÓNÌÍ


Látìgbà tí aago méjìlá onii tí lu ni gbogbo àwọn tó wà lagboole oniroyin káàkiri àgbáyé tí ń fi atẹjiṣẹ ìkíni ranṣẹ sì ọkàn lára àwọn àgbà oniroyin n'ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Adetọpẹ Adeboun, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mọ sì Ọmọọba Samco.

Odu ni Ọmọọba Samco, kíi ṣaimọ f'oloko nìdí iṣẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti ìròyìn lorilẹ-ede Nàìjíríà, pàápàá n'ipinlẹ Ogun. 


Ko si nǹkan méjì tó ń mú káwọn èèyàn máa fi atẹjiṣẹ ìkíni ranṣẹ bí kò ṣe pé òní yìí tíì ṣe ọjọ́ Ẹtì, Fraide, ìyẹn ọjọ́ kẹẹdogun oṣù karùn-ún ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ. 

Ọkàn pàtàkì lára àwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ rédíò ipinlẹ Ogun, ìyẹn Ogun State Broadcasting Corporation, OGBC 90.5FM ni Ọmọọba Samco, to sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alatilẹyin ileeṣẹa wa, AWIKONKO MEDIA CHANNEL to ń gbé Ìròyìn Awikonko jáde.


Bí wọn ba n sọ nípa ẹ̀fẹ̀ àti àwàdà, ẹ̀bùn amutọrunwa lo jẹ́ fún Ọmọọba Samco, nítorí pé gbogbo ara rẹ, ìdúró rẹ, ìjókòó rẹ, yóò máa pá yín lẹ́rìí-ín lai tii bẹ̀rẹ̀ sii sọ̀rọ̀.

'No dull moment' gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn oloyinbo ẹ bá wà pẹ̀lú Ọmọọba Samco, nítorí pé ẹrin arintakiti ni yóò máa fi dáa yín lára yà. 


Ẹ bá wà kí Ọmọọba Adetọpẹ Adeboun, Samco kú oriire ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ tó ń ṣe lónìí. 

Gbogbo àwa òṣìṣẹ́ ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL lo ń gbàdúrà wí pé Ọlọ́run yóò fi ẹ̀mí gígùn àti àlàáfíà pípé tá ọlọjọ-ibi l'ọrẹ. Ẹmi a sì ṣe pupọ rẹ láyé àti láàyè rere.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI