WỌN YAN ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PDP TUNTUN L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 9, 2020

WỌN YAN ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PDP TUNTUN L'OGUN


Ẹgbẹ oṣelu PDP tipinlẹ Ogun ti yan Samson Bamgboṣe gẹgẹ bi alaga fẹgbẹ tuntun fẹgbẹ wọn, ọkunrin naa si tiṣeleri pe gbogbo agbara loun yoo sa lati ri pe ijọba bọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, (APC) lọwọ iyẹn lọdun 2023.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ niluu Abẹokuta, o sọ pẹlu idaniloju pe oun atawọn oloye oun yooku yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu iṣọkan lati rii pe PDP jawe olubori ninu ibo gbogbogboo nipinlẹ Ogun.

Bamgboṣe ni wọn ṣe ibura fun pẹlu awọn oloye tuntun ti wọn yoo ba ṣiṣẹ pọ, awọn naa ni Kẹhinde Ọladẹhinde to jẹ igbakeji alaga, Adeleke Shittu, oun ni akọwe nigba ti Abimbọla Lanre si jẹ olori awọn obinrin.

Rafael Ọlaoṣebika ni olori awọn ọdọ,  Ọlasunkanmi Oyejide ni akọwe olupolongo, Vivian Ogunwo ni olubanidamọran nipa ti ofin, Tomi Anifowose akọwe owo nigba ti Toyin Atọba jẹ akapo.

Bakan naa ni idunuu tun subu layọ awọn oloye ẹgbẹ naa tuntun nigba ti ajọ Ọmọ Ilu iyẹn “Omo-Ilu Foundation”, eyi ti Sẹnetọ Buruji Kashamu da silẹ fun wọn ni mọto tuntun  kọọkan lati le jẹ moriya fun wọn.

Bamgboṣe  to ti figba kan jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ tun sọ siwsju pe lara erongba oun ni pe ki gbogbo ẹgbẹ wa ni isọkan, ki wọn si pada sinu ogo ti wọn ti wa tẹlẹ.

O ni ko sẹni ti ko mọ pe PDP lo n sakoso ipinlẹ yii nigba kan, ko to di pe wahala ṣẹlẹ laarin ọna, ṣugbọn ni bayii awọn ti ṣetan lati mu wahala naa kuro kawọn si pada sinu ogo to ti sa lọ tẹlẹ ninu ẹgbẹ ọhun.

O wa ni iṣẹ akọkọ to wa niwaju oun bayii ni lati ri pe gbogbo awọn to ti sako lọ ni lati pada wa ki wọn jọ ṣejọba lati fi mu ẹni to ba kun oju osuwọn lati dije fun ipo gomina, ninu ibo ọdun 2023.

Lori boya ofin kin yiyan oloye tuntun ti wọn yan lẹyin, alaga tuntun naa sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn yan awọn oloye ba liana ofin ẹgbẹ naa mu. O ni yiyan awọn oloye ti bẹrẹ lati wọọdi si ijọba ibilẹ, ati ẹlẹkunjẹkun, iyẹn Senetorial.

Lati: BOṢERI 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI