Ẹ̀bẹ̀ ni bàbá arúgbó ẹni ọdún mẹrindinlọgọta tí ẹ ń wo yìí ń bẹ ní teṣan ọlọ́pàá báyìí nígbà tọwọ palaba rẹ segi lẹ́yìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lu jìbìtì tán.
Ọkada kan tí wọn pé ní Bajaaji (Bajaj), èyí tí nọ́mbà idanimọ rẹ jẹ WDE 903 VN, to jẹ́ ti ọkùnrin ọlọkada kan, Felix Adeyẹmi ni bàbá náà lọọ fipá gba ni garaaji.
AWIKONKO gbọ pé lójú ẹsẹ̀ tí bàbá náà, ìyẹn Jafaru Ismaila, ọmọ bibi ipinlẹ Adamawa tí de garaaji Warewa tó wà nijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode lo tí yọ káàdì idanimọ tó fi ń lu jìbìtì yìí jáde síta, tó wípé òun yóò gbé Ọkada náà dé teṣan àwọn.
Àwọn tí wọn kò mọ Jafaru gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn ọlọ́pàá tó wà nítòsí ni wọn lọọ ṣe ìwádìí rẹ, tí wọn sì ríi pé kò ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá rí láyé ẹ.
Èyí ló mú káwọn ọlọ́pàá ẹkùn Warewa tọpinpin ẹ, tọwọ sì tẹ ẹ lágbègbè Interchange tó wà lopopona ìlú Èkó sì Ìbàdàn.
B'ọ́wọ́ ṣe tẹ ẹ lo tí bẹ̀rẹ̀ sii bẹbẹ pé kí wọn ṣe òun jẹjẹ torí pé iṣẹ́ ajé lo gbé òun de ipinlẹ Ogun, àti pé òun ti wá lẹ́nu iṣẹ́ náà tipẹ.
No comments:
Post a Comment