WỌN JÙ BAÁLÈ ILÉ TO FIPÁ BA ARỌ LAṢEPỌ L'ỌTA S'ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 10, 2020

WỌN JÙ BAÁLÈ ILÉ TO FIPÁ BA ARỌ LAṢEPỌ L'ỌTA S'ATIMỌLE


Ile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ silu Ọta, ipinlẹ Ogun tí ju baálé ilé ẹni ọdún marundinlogoji {35} kan, Oluwafẹmi Kẹhinde sì atimọle lórí ẹ̀sùn wí pé ó fipá bá arọ laṣepọ. 

Ọjọ́ Iṣẹgun tíì ṣe Tuside àná ni ile-ẹjọ náà ju Kẹhinde sì atimọle náà. Wọn ní ọmọdébìnrin ni arọ tó fipá bá laṣepọ náà. 

Ojúlé kẹrindinlogoji, àdúgbò Success, Abúlé Isalẹ, Ilogbo ni wọn ní Kẹhinde ń gbé, àdúgbò náà lo sì ti fipá bá ọmọdébìnrin náà laṣepọ lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kejì ọdún yìí ni nnkan bí aago mẹ́wàá aabọ alẹ.

Wọn ní ibi tí Kẹhinde tí ń kó ibasun fún ọmọ náà làwọn èèyàn ti ríi, tó sì na pápá bora, ṣùgbọ́n tí wọn padà ríi mú, èyí tó mú kó fojú bá ile-ẹjọ. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kẹhinde sọ pé òun kò jẹbi pẹ̀lú àlàyé, ṣùgbọ́n wọn ní ẹṣẹ tí Kẹhinde ṣẹ̀ tako òfin ọ̀daràn tó ojú ìwé 360, abala kinni t'ọdun 2006.

Onidajọ A. O. Adeyẹmi nígbà tó ń sọ̀rọ̀ sọ pé kí Kẹhinde san owó ìtanràn, ẹgbẹ̀rún lọ́nà aadọta pẹlu oniduro méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn ń ṣàn owó orí wọn déédéé, tí àdúgbò wọn kò jìnnà sí àyíká ile-ẹjọ náà. 

Bẹẹ lo sún igbẹjọ mi-ín sì ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù yìí.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI