Ọba David Oyerinọla Adedunmoye tí ṣàpèjúwe Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq gẹ́gẹ́ bí gomina tí kì í pariwo síta lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó ń ṣe káàkiri ipinlẹ náà.
Ó ní adarí tí ọ̀rọ̀ igbayegbadun aráàlú jẹ lógún púpọ̀ ni Gómìnà AbdulRazaq jẹ pẹ̀lú bo ṣé fi àwọn aráàlú ṣe àkọ́kọ́ látìgbà tó ti ń ṣàkóso.
Ọba Oyerinọla Adedunmoye tó jẹ́ Elerin tilu Adanla-Irese lo yannanaa ọ̀rọ̀ yìí síta lásìkò tó ń gba igbimọ National Agricultural Land Development Authority (NALDA) tí wọn ń bójútó àkànṣe iṣẹ́ àwọn àgbègbè Ààfin Adedunmoye.
NALDA là gbọ pé wọn tí yàn ipinlẹ Kwara láti mú ọ̀rọ̀ àgbẹ̀ àwọn ọdọ, ìyẹn National Youth Farmers of Nigeria (NYFN), eyi ti wọn fẹ ẹ bẹrẹ l'awọn ijọba mẹta n'ipinlẹ naa.
Ọba Oyerinọla sọ pe ọpọ awọn iṣẹ ni Gomina AbdulRazaq n ṣe kaakiri ipinlẹ naa, ti ko si mu ariwo dani, ati pe gbogbo ẹka ati agbegbe ipinlẹ naa ni akanṣe iṣẹ ti nlọ lai pariwo, to si ni bo ṣe yẹ k'ijọba gidi ṣe ri niyẹn.
No comments:
Post a Comment