AṢIRI CHIDI TO N FI ỌTI GBA ỌKADA N'IPINLẸ OGUN TU, IPINLẸ ANAMBRA NI WỌN LO TI N WA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 13, 2020

AṢIRI CHIDI TO N FI ỌTI GBA ỌKADA N'IPINLẸ OGUN TU, IPINLẸ ANAMBRA NI WỌN LO TI N WA

Eyi yẹ ko kọ awọn ọlọkada ti wọn fẹran ọti mimu lọgbọn gidigidi, ki wọn si yee gbẹkẹle awọn ọrẹ ojiji ti wọn n ba pade.

Ọjọ Mọnde to kọja yii ni aṣiri awọn baale ile meji kan, Chidi Umeh ati Obinna Onyebuchi tu lagbegbe Owode-Yewa, ipinlẹ Ogun, ọti la gbọ pe wọn n ra f'awọn ọlọkada ki wọn too ji ọkada wọn gbe salọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Chidi yoo ti fi oogun orun sinu ọti naa ko to o gbe e fun ọlọkada to ba ti fẹẹ gba ọkada lọwọ, lẹyin to ba ti ba wọn ṣe ọrẹ tipatipa.

Ilu Nnewi to wa n'ipinlẹ Anambra la gbọ pe Chidi maa n wa ji ọkada gbe n'ipinlẹ Ogun, ti yoo si lọ tun awọn ẹya-ara ọkada naa ta f'awọn eeyan ẹ.

Ninu atẹjade ti alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fi sita nipa awọn eeyan naa lo ti sọ pe pẹlu iranlọwọ awọn araalu lọwọ fi tẹ Chidi ati Obinna, ti wọn si jẹwọ bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ wọn.

Oyeyẹmi sọ pe ọga awọn Edward A. Ajogun ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lori wọn, to si ti gba awọn ọlọkada at'awọn awakọ elero lamọran nipa gbigba nnkan jẹ tabi mu lọwọ awọn ti wọn ko mọ ri.

 Eyi to n ya awọn eeyan lẹnu pupọ bayii ni bi Oyeyẹmi ṣe tun sọ siwaju ninu ọrọ rẹ pe ọlọkada ti Chidi ati Obinna gba ọkada lọwọ ẹ ṣi n sun lasiko toun fi ọrọ naa to wa leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI