AYEDERU PASITỌ L'AWỌN TI KO TII ṢILẸKUN ṢỌỌṢI WỌN SILẸ - ỌYAKHILOMẸ PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 21, 2020

AYEDERU PASITỌ L'AWỌN TI KO TII ṢILẸKUN ṢỌỌṢI WỌN SILẸ - ỌYAKHILOMẸ PARIWO SITA

Alaṣẹ ati oludasiẹ ṣọọṣi LoveWorld Incorporated t'awọn eeyan mọ si Christ Embassy, Pasitọ Chris Ọyakhilomẹ ti pariwo sita pe ayederu l'awọn pasitọ ti wọn ko ti i ṣilẹkun ṣọọṣi wọn silẹ fun isin lati bẹrẹ.

Latigba ti ijọba orilẹ-ede Naijiria pẹlu awọn ijọba ipinlẹ kọọkan ti sọ pe ki gbogbo eto pada si bo ṣe wa tẹlẹ, ṣugbọn pẹlu awọn ayipada diẹ-diẹ lojuna lati dẹkun itankalẹ arun Covid-19 l'awọn alakoso ṣọọṣi kan ti sọ pe ko tii to asiko t'awọn yoo ṣilẹkun silẹ.

Ojọ kinni oṣu kẹfa ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe k'awọn ile ijọsin bẹrẹ isin wọn nibamu pẹlu ofin ati ilana lati dẹkun arun naa.

Bi ọrọ Aarẹ Buhari ṣe jade sita l'awọn pasitọ bi i Tunde Bakare, TB Joshua ati Sam Adeyẹmi ti sọ pe awọn ko ti i le fidi rẹ mulẹ pe arun naa ti kasẹ nilẹ patapata, fun idi eyi ni wọn ṣe sọ pe bi asiko ba to l'awọn yoo to ṣilẹkun silẹ.

Ọyakhilomẹ ninu ọrọ rẹ sọ pe o ṣe oun laanu pe awọn ṣọọṣi kan wa toun ti ro pe ṣọọṣi ni wọn, ṣugbọn ti ko ri bẹẹ.

"A ri awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn n pariwo pe k'awọn ile ijọsin wa ni titi pa, eyi lo fi han daju iru awọn nnkan ti ṣọọṣi jẹ. Ṣe wọn gbagbọ ninu Ọlọrun ṣa, Ọlọrun kan naa ti a ri ka ninu Bibeli?

"Mo ti gbọwọ le awọn to ni arun yii lori kaakiri agbaye lai ni ibẹru wi pe maa ko arun naa. Ọrọ Ọlọrun fi idaniloju Kristi han...

"O le jẹ oniwaasu ṣugbọn ẹru ati aigbagbọ to wa lọkan ẹ ti fi ẹ sinu igbekun. Bi Jesu ba jẹ otitọ, ti o si n gbe inu ẹ, ṣe ko yẹ ki iwọ naa jẹ oluwosan bi? Ṣe o yẹ ki o bẹru?"

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI