ỌPẸ O, IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ KWARA ATI IYAWỌ RẸ BỌ LỌWỌ ARUN KORONAFAIRỌỌSI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 29, 2020

ỌPẸ O, IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ KWARA ATI IYAWỌ RẸ BỌ LỌWỌ ARUN KORONAFAIRỌỌSI


'Ko s'ọba bi i rẹ Oluwa, a dupẹ oore rẹ' l'orin t'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara n gba fun igbakeji Gomina ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Kayọde Alabi ati iyawo rẹ lori bi wọn ṣe bọ kuro lọwọ ajakalẹ arun Koronafairọọsi.
 
Ayẹwo Covid-19 ti wọn ṣe fun t'ọkọ-t'iyawo naa f'idi rẹ mulẹ wi pe arun naa ti dagbere patapata fun wọn, ti ko si le pada wa mọ.
 

Lati nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin n'iroyin naa jade sita wi pe igbakeji Gomina ati iyawo rẹ ti lugbadi arun naa, to si jẹ pe latigba naa lawọn eeyan ti wọle adura fun wọn, ti wọn si n gbadura tọsan-toru fun wọn.

Ijọba ipinlẹ Kwara lo kede iroyin naa sita lori ikanni ayelujara ti Twitter wọn ni alẹ ana wi pe ki wọn ba wọn yọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI