LẸ́YÌN ỌDÚN KẸTA, ṢEUN ẸGBẸGBẸ TÚN F'OJÚ BA ILÉ-ẸJỌ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 15, 2020

LẸ́YÌN ỌDÚN KẸTA, ṢEUN ẸGBẸGBẸ TÚN F'OJÚ BA ILÉ-ẸJỌ́


Ọjọ́ kẹfà oṣù kẹwàá ọdún yìí ni Ṣeun Ẹgbẹgbẹ ni gbajugba makẹta nni, Ṣeun Ẹgbẹgbẹ yoo tun pada f'oju ba ile-ẹjọ lẹyin ọdun mẹta to ti wa lahamọ awọn ọlọpaa lori ẹsun jibiti ati gbajuẹ.
 
Ile-ẹjọ giga apapọ to wa nilu Eko lo sọ pe ohun yoo tun dide lori ẹjọ naa lori ẹsun ti wọn fi kan Ẹgbẹgbẹ.

Bẹ o ba gbagbe, laarin ọdun 2015 si ọdun 2017 lọwọ tẹ Ṣeun Ẹgbẹgbẹ lẹyin to lu awọn mala to n ṣe paṣipaarọ owo ile okeere nilu Eko.

Ẹsun ogoji ọtọọtọ ni wọn fi kan Ṣeun at'awọn ẹmẹwa rẹ bi i Oyekan Ayọmide, Lawal Kareem, Ọlalekan Yusuf ati Muyideen Ṣoyọmbọ, ti Onidajọ Olurẹmi Oguntoyinbo si fi aanu wo Ṣeun pẹlu beeli miliọnu marun naira, ṣugbọn ti ko pada ri san.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI