ỌPẸ O! LẸYIN IKU BỌBISKY, AWỌN ARAALU DANA ARIYA RẸPẸTẸ NI RIVERS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 15, 2020

ỌPẸ O! LẸYIN IKU BỌBISKY, AWỌN ARAALU DANA ARIYA RẸPẸTẸ NI RIVERS


Idunnu nla lo ṣubu lu ayọ awọn ara ipinlẹ Rivers n'igba ti wọn pe gbajugbaja ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to ti n da wọn laamu lati bi ọdun meloo kan sẹyin ti jade laye lẹyin ikọlu oun pẹlu awọn ọlọpaa.

Honest Digbara t'ọpọ awọn eeyan mọ si Bọbisky lorukọ ẹ, ti a si gbọ pe o ti pẹ t'awọn ọlọpaa ti n wa a, koda, ti wọn ni Gomina wọn, Nyesom Wike naa tun gbe miliọnu lọna ọgbọ naira silẹ fẹnikẹni to ba ri Bọbisky mu.

Nigba tọwọ maa tẹ ẹ, a gbọ pe ṣe doju ija kọ awọn ọlọpaa loru Satide ọsẹ to kọja yii, ṣugbọn ti wọn pada gba agbara lọwọ ẹ ni tipatipa.

Bi iroyin naa ṣe jade sita l'awọn araalu ti dana ariya rẹpẹtẹ, ti wọn si n kọrin ọpẹ si Ọlọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI