DAPỌ ABIỌDUN YAN AWỌN ALAKOOSO TUNTUN FUN ỌSIBITU ỌLABISI ỌNABANJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 7, 2020

DAPỌ ABIỌDUN YAN AWỌN ALAKOOSO TUNTUN FUN ỌSIBITU ỌLABISI ỌNABANJỌ


Gomina Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun lonii ti yan awọn igbimọ agba tuntun ti yoo maa ṣakoso ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ, iyẹn Ọlabisi Ọnabanjọ University Teaching Hospital (OOUTH) to wa nilu Ṣagamu, ipinlẹ naa.
 
Nibẹ lo ti gba awọn igbimọ agba tuntun naa lamọran wi pe ki wọn mu iṣẹ wọn lokunkundun fun itẹsiwaju ati idagbasoke ọsibitu naa, ko le di ohun aritọka rere si lawujọ.
 
Awọn igbimọ naa ni: Dọkita Adekunle Hassan to jẹ alaga; Dọkita (Arabinrin) Bisọla Shodipọ-Clark; Lekan Asuni; Ọgbẹni Ṣolu Abimbọla; Dọkita Peter Adefuye to jẹ Dọkita agba (Chief Medical Director), OOUTH; Ọjọgbọn Tọla Ọlatunji toun jẹ Provost fun College of Health Sciences (OOUTH).
 
Awọn mi in ni: Ọjọgbọn Adediwura Fred Jaiyesimi toun n ṣoju ile igbimọ aṣofin OOU; Ọjọgbọn Ayọdeji Johnson Agboọla to jẹ igbakeji giwa (OOU); Dọkita (Arabinrin) Bunmi Fatungaṣe Chair; Dọkita Oluwọle. O. Kukọyi; Ọgbẹni Sammy Ogunjimi; Dọkita Sọlomọn O. Ṣokunbi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI