Agbẹjọ́rò ni Ìgbòho yóò lò tó oṣù kan gbáko lẹ́wọ̀n Benin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 27, 2021

Agbẹjọ́rò ni Ìgbòho yóò lò tó oṣù kan gbáko lẹ́wọ̀n Benin


Ọkàn lara awọn agbẹjọro Sunday Igboho nilẹ Benin to ba akọroyin BBC Pidgin sọrọ laipẹ yii ti sọ pe ọkunrin naa yoo lo to oṣu kan gbako lẹwọn ti wọn fi pamọ si.

Ninu ọrọ to ba BBC Pidgin sọ lori foonu, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Igboho ko ni nnkan ṣe pẹlu ijọba Naijiria, ati pe wọn fẹẹ tubọ ṣe iwadii rẹ daadaa boya ko lẹbọ-lẹru niluu wọn.

Ẹ gbọ ifọrọwerọ naa nibi 👉 ÌGBÒHO ati BBC

Ọkunrin naa tun sọ pe bi Igboho ko ba lo ọsẹ kan, tabi ọsẹ meji, tabi ọsẹ mẹta, o daju pe yoo lo oṣu kan gbako lẹwọn ti wọn fi si.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI