Ayé ò! Wọ́n tún jí ọgọ́rùn-ún èèyàn lọ lọ́jọ́ kan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 26, 2021

Ayé ò! Wọ́n tún jí ọgọ́rùn-ún èèyàn lọ lọ́jọ́ kan ṣoṣo


Awọn agbebọn kan niroyin tun fi to wa leti bayii wi pe wọn ti ji awọn ti ko din ni ọgọrun-un lọ loju ọna Ṣokoto lọjọ Aiku, Sannde ana.
 
Nibi ikọlu naa la gbọ pe wọn tun ti pa eeyan meji, ko to di pe wọn ji awọn yooku salọ, ti ko si ti i ṣeni to le sọ pao ibi ti wọn wa titi dasiko ta a pari iroyin yii.
 
Ọna meji ọtọọtọ la gbọ pe awọn agbebọn naa ti ji awọn eeyan yii gbe nipinlẹ Ṣokoto. Lara awọn ti a gbọ pe awọn agbebọn naa ti gbegi dina ni oju ọna Ṣokoto silu Gusau, nibi ti wọn ti ji awọn ti ko din ni ọgọta gbe.

Bakan naa ni wọn tun gbegi dina loju ọna Wurno si Goronyo, nibi ti wọn paayan meji danu, ti wọn si ji awọn eeyan rẹpẹtẹ lọ.
 
Alaga ẹgbẹ awakọ kan nipinlẹ Ṣokoto, iyẹn Sokoto Mass Transit, Yahuza Abubakar Chika, lo pariwo yii sita lalẹ ana, Sannde, to si jẹ ko ye gbogbo aye wi pe wọn ti ji awọn eeyan to wa ninu ọkan lara awọn mọto wọn gbe salọ.

O ni awakọ ati ẹnikan ṣoṣo ni ori ko yọ, nitori pe wọn raaye na papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI