Ẹ dákẹ́ rúmọ́ọ̀sì, ìpàdé gbogboogbò máa wáyé ní Kwara lónìí - APC pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 31, 2021

Ẹ dákẹ́ rúmọ́ọ̀sì, ìpàdé gbogboogbò máa wáyé ní Kwara lónìí - APC pariwo síta


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Kwara lonii ti sọ pe kawọn eeyan ma ṣe feti si awuyewuye wi pe ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa ko ni i waye lonii.

Ninu atẹjade Alaaji Tajudeen Aro Fọlaranmi, to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe iroyin ẹlẹjẹ kan ti n fo kaakiri igboro wi pe wọn ti wọgile ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara ati ipinlẹ meji lorilẹ-ede yii.
 
O ni irọ nl to jinna si otitọ ni, nitori pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara.
 
Alaaji Fọlaranmi sọ pe bi wọn ti ṣe laa kalẹ ni ipade naa yoo ṣe waye lai ni idiwọ kankan nipinlẹ Kwara atawọn ipinlẹ meji ti wọn n sọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI