Ẹ tún gbọ́ ọ̀nà tuntun tíjọba Nàìjíríà fẹ́ẹ́ fi gba Ìgbòho kúrò lọ́wọ́ ìjọba Benin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 29, 2021

Ẹ tún gbọ́ ọ̀nà tuntun tíjọba Nàìjíríà fẹ́ẹ́ fi gba Ìgbòho kúrò lọ́wọ́ ìjọba Benin


Ijọba orilẹ-ede Naijiria ni iroyin tun fi to wa leti bayii wi pe wọn tun ti n wa ọna tuntun mi in lati gba Oloye Sunday Adeyẹmọ, iyẹn Sunday Igboho, olori ajijangbara fun ominira ilẹ Yoruba kuro lọwọ ijọba orilẹ-ede olominira Benin.
 
Bẹ o ba gbagbe, lati nnkan bi oṣu kan bayii ni ijọba Naijiria ti n wa gbogbo ọna lati rọwọ to ọkunrin naa, ṣugbọn ti gbogbo rẹ n ja si pabo, paapaa nigba ti awọn ọlọpaa Interpol rọwọ to Igboho lakooko to fẹ maa gba orilẹ-ede naa lọ si Germany.
  
Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii fi ye wa pe aṣoju orilẹ-ede Naijiria silẹ benin, Ajagunfẹyinti Tukur Buratai ti lọọ ba Aarẹ orilẹ-ede Benin, Patrice Talon lati fun un ni lẹta gẹgẹ bi aṣoju Naijiria si Benin, to si ni awọn fẹ ki ajọṣepọ wọn tubọ danmọnran ju ti tẹlẹ lọ.
 
Lẹta naa, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Credence Letter ni wọn tun sọ pe yoo jẹ ki ijọba Naijiria ati Benin tọwọ bọwe adehun tuntun, ki ajọṣepọ tun le maa gbooro si i.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrin, oṣu keji ọdun yii ni Aarẹ Buhari fi orukọ Buratai ranṣẹ sile igbimọ aṣofin orilẹ-ede yii, ṣugbọn ti Buhari pada kede rẹ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa to kọja lọ.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ko si nnkan meji to jẹ ki Buratai mu lẹta naa lọ, bi ko ṣe nitori Sunday Igboho to wa lahamọ lorilẹ-ede Benin, bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi rẹ mulẹ lakooko ta a pari iroyin yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI