Ìjà àgbà ẹgbẹ́ òkùnkùn làwọn eléyìí ń jà kọ́wọ́ tó tẹ̀ wọ́n l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 19, 2021

Ìjà àgbà ẹgbẹ́ òkùnkùn làwọn eléyìí ń jà kọ́wọ́ tó tẹ̀ wọ́n l'Ógùn


Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ ọga wọn, Edward Awolọwọ Ajogun ti sọ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori awọn mẹrin tọwọ tẹ yii lori ẹsun wi pe wọn n ṣe ẹgbẹ okunkun ti wọn fi kan wọn, sibẹ, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ki wọn gbagbe sẹwọn nitori wahala ojoojumọ ti wọn n da silẹ niluu.
 
Opin ọsẹ to kọja yii lọwọ palaba awọn mẹrẹẹrin ti wọn pe orukọ wọn ni: Oluṣẹgun Ọwọọla, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26); Gbenga Akinkade, ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn (34); Jinadu Waliu, ọmọ ọgbọn ọdun (30) ati Sanni Hammẹd, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn (27) seg.
 
Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ati Ẹiyẹ la gbọ pe wọn kọju ija agba sira wọn lagbegbe Atan-Ọta, ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti n fi ibọn atawọn nnkan ija oloro le ara wọn kaakiri.
 

Nnkan bi aago mẹrin oru la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye, to si mu kawọn ara agbegbe naa ranṣẹ sawọn ọlọpaa, ti wọn fi lọ ko wọn. Mẹrin pere lọwọ tẹ ninu wọn, tawọn yooku si raaye na papa bora.
 
Ibọn, ọta ibọn, ọbẹ meji, irin atawọn oogun abẹnugọngọ lawọn ọlọpaa gba lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI