Ìkúnlẹ̀ abiyamọ o! Èèyàn mẹ́rìnlá pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ọ́ṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 18, 2021

Ìkúnlẹ̀ abiyamọ o! Èèyàn mẹ́rìnlá pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ọ́ṣun


Ko din ni eeyan mẹrinla ti wọn ti dagbere faye lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii ninu ijamba ọkọ to waye lagbegbe Powerline to wa lopopona Ipetu-Ijẹṣa si Ileṣa nipinlẹ Ọṣun.

Nnkan bi aago mẹfa ku ogun iṣẹju la gbọ pe la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye laaarin mọto Sienna ati tanka elepo.

A gbọ pe asiko ti awakọ Sienna ti nọmba idanimọ rẹ jẹ KRD 842 GY n gbiyanju lati sare kọja tanka Howo Sinotruck ti nọmba idanimọ rẹ jẹ BAU 171 ZE, ni ọrọ gba ibomiran yọ.

Ṣe la gbọ pe tanka naa gba mọto yii debi wi pe eeyan mẹrinla jade laye, to si jẹ pe awọn meji pere lori ko yọ.

Ọmọ kekeeke mẹfa, ọkunrin mẹrin, obinrin mẹrin ti wọn jẹ agbalagba ni wọn ba iṣẹlẹ ajalu ọhun lọ.

Agnes Ogungbemi to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ajọ ẹṣọ popona tijọba apapọ, Federal Road Safety Corps (FRSC), to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe awọn ti ko oku awọn eeyan naa lọ si mọṣuari ọsibitu Wesley to wa niluu Ileṣa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI