Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún pokùnso nítorí èsì ìdánwò rẹ̀ tì kò dára - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, July 22, 2021

Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún pokùnso nítorí èsì ìdánwò rẹ̀ tì kò dára


Ọmọ ọdun mẹẹdogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Daphine Kimuli la gbọ pe o ti gbẹmi ara rẹ bayii nitori esi idanwo rẹ, eyi to ṣe, ti ko tẹẹ lọrun.

Kimuli la gbọ o ṣe idanwo aṣekagba kuro nile ẹkọ alakọọbẹrẹ ti Bwikya Muslim Primary School to wa ni Hoima City, orilẹ-ede Uganda lọdun to kọja.

Ọjọ kẹrindilogun, oṣu yii ni wọn sọ pe ajọ to n mojuto idanwo lorilẹ-ede naa, Uganda National Examination Board (UNEB) gbe esi idanwo jade.

Wọn ni Kimuli ṣe lọ yẹ esi idanwo rẹ wo, lo ri i pe oun ko ṣe daadaa rara, ida marundinlọgbọn ninu ọgọrun-un ni wọn loo gba 

Bo ṣe ri eyi, ni wọn loo binu kuro nile fun ọjọ mẹta gbako, ko to di pe wọn pada ri oku rẹ lori igi to so ara rẹ kọ si.

Gbogbo akitiyan ti wọn lawọn obi rẹ ṣe lati ri i, ni wọn lo ja si pabo, lẹyin ti wọn tun ti fi to awọn agbofinro leti wi pe awọn ko mọ bo ṣe poora ninu ile.

Itosi ile to n gbe pẹlu awọn obi rẹ la gbọ pe o pokun so si, iyẹn ni Bwikya ward, Hoima East division.


Ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbe ladugbo,  ni wọn lo ri oku rẹ l'Ọjọru, Wẹside ana, lori igi to ku si.

Agbẹnusọ ọlọpaa Albertine, Ọgbẹni Julius Hakiza, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe Kimuli fi lẹte pelebe kan silẹ ko to o gbe igbesẹ yii.

O ni ṣe lo darukọ gbogbo awọn to fi ṣe ẹlẹya nipa esi idanwo rẹ ti ko dara naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI