Iléyá, Kò sí ǹnkan tó dà bi àlàáfíà àti ìṣọ̀kan - Gómìnà AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 20, 2021

Iléyá, Kò sí ǹnkan tó dà bi àlàáfíà àti ìṣọ̀kan - Gómìnà AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ti sọ pe ko si ọna abuda sibi alaafia ati ifọkanbalẹ laaarin ilu, bi ko ṣe ọna lati ifẹ ati iṣọkan laaye.
 
Kete ti wọn pari eto adura ọdun Ileya ti wọn ṣe niluu Ilọrin ni Gomina AbdulRazaq ti sọrọ ọhun ko to lọ si aafin Ẹmir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari lati lọ ki i.
 
O ni ko sibi meji ti idagbasoke ati ilọsiwaju ti maa n de ba ilu bi ko ṣe ibi ti afẹfẹ ifẹ, iṣọkan ati alaafia ti n fẹ.

"Amọran alaafia ni mo fẹẹ fun awọn eeyan wa. Ilu iṣọkan la wa yii, ti a si gbọdọ ni lati jẹ ko wa bẹẹ. Awọn baba-nla wa ṣiṣẹ takun-takun lati ri i pe alaafia jọba nipinlẹ yii, awa naa yoo si gbọdọ maa mu idagbasoke ba alaafia nipinlẹ wa."
 
Bakan naa ni AbdulRazaq tun gbe oriyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọna to n gba gbogun ti iwa ọdaran lorilẹ-ede yii.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI