Nítorí Ìgbòho! Ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà yawọ Kútọnu, wọ́n lẹ́gbẹ́ Ìṣọ̀kan Ọmọ Odudua ló rán wọn lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 25, 2021

Nítorí Ìgbòho! Ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà yawọ Kútọnu, wọ́n lẹ́gbẹ́ Ìṣọ̀kan Ọmọ Odudua ló rán wọn lọ


Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Iṣọkan Ọmọ Odudua ti dide iranlọwọ fun gbogbo awọn ti wọn fẹẹ lọ siluu Cotonou lorilẹ-ede olominira Benin lati lọ ṣatilẹyin fun Oloye Sunday Adeyẹmọ, iyẹn Sunday Igboho.

Ọla ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde ni ẹjọ naa yoo tẹsiwaju nile ẹjọ Cour De’appal De Cotonou
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ẹgbẹ Iṣọkan Ọmọ Odudua naa gbe mọto silẹ lọfẹẹ, ti wọn tun pese ibi ti wọn yoo de si nilẹ Benin fun gbogbo wọn, paapaa ibi ti wọn yoo sun si.
 
Pupọ awọn ọmọ Naijiria si la gbọ pe wọn ti wa niluu Benin bayii, iyẹn lakooko ta a pari iroyin yii.

A gbọ pe awọn ti ko din ni ọgbọn ni ẹgbẹ naa ti ran lọ, iyẹn ninu atẹjade ti wọn gbe jade lonii
 
“Ẹ ma jẹ ki wọn tan yin, a ṣi nilo awọn eeyan rẹpẹtẹ niluu Benin lati le jẹ ki wọn mọ pe Igboho ki i ṣe ọdaran. A ti ni awọn ọgbọn bayii nilẹ Benin. Ẹ le pe awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyii bi ẹ ba fẹ mọ adirẹẹsi ati ibi ti ẹ maa de si.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI