Nítorí Igboho: Ọọ̀ni Ilé-ifẹ̀ ṣe ìpàdé ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lù àwọn àgbà ilẹ̀ Yorùbá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 21, 2021

Nítorí Igboho: Ọọ̀ni Ilé-ifẹ̀ ṣe ìpàdé ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lù àwọn àgbà ilẹ̀ Yorùbá


Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ti jẹ ko ye wa pe, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji ti bẹrẹ ipade pọ pẹlu awon agbaagba ilẹ Yoruba, lori ọna lati gba Oloye Sunday Adeyẹmọ, iyẹn Sunday Igboho silẹ lọwọ ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ana, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee la gbọ pe Ọba Adeyẹye, Arole Oduduwa ṣe ipade naa papọ pẹlu awọn agbaagba ilẹ Yoruba.

Nibẹ ni wọn ti sọrọ lori iṣoro to n dojukọ ilẹ Yoruba lọwọlọwọ, paapaa lori ọrọ Oloye Sunday Igboho, olori ajijangbara fun ominira awọn ọmọ Yoruba kuro lọwọ ijọba amunisin.

Awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti ko din ni ọgbọn la gbọ pe Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye wọle ipade pọ pẹlu.

Lara wọn ni Sẹnetọ Abiọdun Olujimi, Akin Ọṣuntoun to jẹ oludamọran pataki labẹ iṣakoso Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, oludije sipo gomina nipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Jimi Agbaje atawọn mi in.

Igbakeji alaga igbimọ awọn ọba alaye nipinlẹ Ọyọ, Ọba Francis Alao, Olugbọn tilu Orile-Igbọn lo fidi ipade naa mulẹ.

Ọba Alao ni, bo tilẹ jẹ pe nipa ọrọ idagbasoke ilẹ Yoruba ni ipade naa wa fun un, ṣugbọn tawọn tun ni lati sọrọ lori bi awọn agbofinro ṣe mu Oloye Sunday Igboho

“Koko ipade wa ti Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi pe ni lati pada si ipilẹṣẹ wa,ka si maa ṣe awọn nnkan ti a n ṣe lati ibẹrẹpẹpẹ.

“Ọpọ nnkan ni ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ lati nnkan bi ọdun meloo sẹyin lorilẹ-ede yii, nipa oṣelu, eto ọrọ aje, awujọ, a si fẹ ki nnkan wa bo ṣe yẹ ko lọ. Ọrọ Igboho naa wa ninu ohun ti a sọ.

"Ọrọ Igboho ki i ṣe nnkan ti a pe ipade le lori, ṣugbọn a ko le gbe e ti sẹgbẹ. A ni lati wa niwaju niju ohun gbogbo to n ṣẹlẹ lorilẹ-ede yii. A ṣi maa tubọ ṣe ipade rẹpẹtẹ, debi pe a maa jẹ ki awọn tọrọ kan bi i awọn eeyan, ẹgbẹ atawọn mi in lati le jẹ ka fi ohun gbogbo soju ọna to yẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI