O ma ṣe o won yinbon pa Babatunde n'Ibadan, lẹyin to pari idanwo aṣekagba rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, July 27, 2021

O ma ṣe o won yinbon pa Babatunde n'Ibadan, lẹyin to pari idanwo aṣekagba rẹ

 

Nibi ija awọn ọmọ okunkun kan ti wọn loo waye nile itaja igbolode kan to wa lagbegbe Ring-Road, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ la gbọ pe wọn ti pa gendekunrin ti ẹ n wo yii.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni ni nnkan bi agogo mẹjọ aabọ alẹ, ọjọ Aiku, Sannde lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun le ara wọn wọ ile iataja igbalode ta a forukọ bo laṣiri yii.
 
Ibi ti wọn si ti n fa ọrọ wọn ni wọn ti yinbọn pa Akinọla Babatunde, ẹni ti wọn lo ṣẹṣẹ pari idanwo aṣekagba rẹ ni fasiti.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa nigba to n gba ẹnu alukoro wọn, Adewale Ọṣifẹsọ, sọrọ sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii wọn lati le rọwọ to gbogbo awọn ti wọn wa nidi iku Akinọla.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI