Ó tán o! Sàlámì tú àṣírí ẹ̀sùn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tíjọba Nàìjíríà fi kan Ìgbòho ni Benin kó tó di pé wọ́n mu ní Kútọnu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 25, 2021

Ó tán o! Sàlámì tú àṣírí ẹ̀sùn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tíjọba Nàìjíríà fi kan Ìgbòho ni Benin kó tó di pé wọ́n mu ní Kútọnu

 
Agbẹjọro Oloye Sunday Igboho, Ibrahim David Salami ti tu aṣiri tuntun nipa ẹsun ti ijọba orilẹ-ede Naijira fi kan ọkunrin naa lọdọ ijọba ilẹ Benin.
 
Salami sọ pe ki i ṣe pe ijọba Benin dee de mu Igboho, bi ko ṣe pe awọn ẹsun nla ti wọn fi kan Igboho lọdọ ijọba Benin lo jẹ kawọn naa pinnu lati mu, bi bẹẹ kọ, wọn ko ba ti maa woran ni ti wọn.

O ni ẹsun wi pe Igboho n ko ibọn ati nnkan ija oloro wọ orilẹ-ede Naijiria ni ijọba Naijiria fi kan Igboho lọdọ ijọba Benin.

Yatọ si eyi, o tun sọ pe ẹsun mi in ti ijọba Naijiria tun fi kan olori ajijangbara fun ominira ilẹ Yoruba ni pe o n da ogun silẹ, o si fẹẹ pin Naijiria si meji tabi mẹta.
 
“Ijọba Naijiria sọ pe Igboho n ṣe fayawọ ibọn ati nnkan ija oloro wọ Naijiria. Ẹsun keji ni pe o n da wahala silẹ, ti ko si jẹ kijọba roju raaye ṣiṣẹ.

“Ẹsun kẹta ni pe Igboho n gbiyanju lati pin orilẹ-ede Naijiria si meji abi mẹta, eyi tawọn ko le laju silẹ maa woran.”

Siwaju si i ni Salami sọ pe o tẹ oun lọrun ki Sunday Igboho ku si orilẹ-ede Benin, ju ki ijọba Naijiria rọwọ to o lọ.
 
O ni gbogbo nnkan ti yoo ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe wọn ko gbe Igboho pada wa si Naijiria.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI