Òpin débá ayé fàmílétè-ki-n-tutọ́ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn n jẹ nipinlẹ Ogun - Abíọ́dún pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 18, 2021

Òpin débá ayé fàmílétè-ki-n-tutọ́ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn n jẹ nipinlẹ Ogun - Abíọ́dún pariwo síta


Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ti sọ pe gbogbo aye fàmílétè-ki-n-tutọ́ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kaakiri ipinlẹ Ogun ti dopin, nitori pe igbesẹ to lọọrin lo ti bẹrẹ lati gbogun ti wọn patapata.

O ni ki gbogbo awọn to ba wa ninu ẹgbẹ okunkun naa tete lọ jawọ, tabi ki gbogbo awọn to n gbero lati darapọ mọ ẹgbẹ buruku naa tete ronupiwada, ki wọn si tun ero wọn pa, nitori pe opin ti de ba wọn patapata.

Ilu Odogbolu, ijọba ibilẹ Odogbolu ni Gomina Abiọdun ti sọrọ yii nita gbangba, iyẹn nibi ipolongo idibo ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to ṣe lọ lanaa, Abamẹta, Satide.

O ni laipẹ, awọn yoo gbe igbimọ ara ọtọ (Special Task Force) dide lati gbogun ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ́ okunkun patapata ti wọn n da alaafia awọn araalu laamu.

Siwaju si i lo sọ pe ijọba oun ko ni i laju silẹ mọ lati jẹ ki awọn oniṣẹ ibi maa ba gbogbo idagbasoke to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa jẹ.

"Inu mi dun lati sọ fun un yin lonii wi pe ko si nnkan to n jẹ ibọn yinyin mọ. Ẹ maa ri i pe wahala ẹgbẹ oṣelu ti dinku patapata. Inu wa n dun, a si ni ifọkanbalẹ. Gbogbo wa ni okoowo wa n lọ bo ṣe yẹ. Ko si akọsilẹ ipaniyan.

"Ṣugbọn awọn ọmọ kekeeke kan wa ninu ẹgbẹ okunkun, Bi mo ba dawọ lee yin...haaah! Mo maa gbe igbimọ dide lodi si ẹgbẹ okunkun. Ipinlẹ yii yoo si jẹ akọkọ lorile-ede yii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI