Sanwo-Olu sọ ohun tí wọ́n ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 24, 2021

Sanwo-Olu sọ ohun tí wọ́n ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho


Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti sọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lori ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho.
 
Lonii ni Gomina Sanwo-Olu sọrọ naa jade nibi to ti lọ dibo, iyẹn ni wọọdu kẹjọ, ibudo idibo kọkandinlogun, Ikoyi keji nipinlẹ Eko.

Sanwo-Olu ni awọn eeyan ti wa lori ọrọ Oloye Sunday Igboho, eyi ti ko nidii kan ni pato tawọn yoo fi sọ ipinnu ati igbesẹ naa jade sita fẹnikẹni.

"Asiko to le ree fun gbogbo wa. Mo le fi da yin loju wi pe awọn eeyan n ṣiṣẹ takuntakun labẹlẹ. Niru awọn iṣẹlẹ bayii, ki i ṣe nipa pipe awọn akọroyin si nnkan ti a n ṣe."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI