Nítorí Hushpuppi, wọ́n ti dá Abba Kyari dúró nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 1, 2021

Nítorí Hushpuppi, wọ́n ti dá Abba Kyari dúró nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá


Ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii, Usman Alkali Baba ti sọ pe ki gbajugbaja ọlọpaa nni, DCP Abba Kyari, lọọ jokoo sile titi ti yoo fi yanju ọrọ ẹsun jibiti tijóba ilẹ Amẹrika fi kan an.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede yii, Frank Mba gbe jade, o ni Kyari ṣi maa wa lẹnu iṣẹ ọlọpaa digba ti iwadii yoo fi pari, ṣugbọn ti ko ni i ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọlọpaa mọ.
 
Lẹta naa to jade lanaa, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje to jọja yii lo ti sọ pe Kyari yoo jokoo sile digba ti ẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an yoo fi pari.
 
Nibẹ naa lo tun ti sọ pe awọn ti gbe igbimọ iwadii dide lati gbe ẹsun naa yẹwo lati mọ eyi to jẹ otitọ ati okodoro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI