Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀: Olukere tìlu Odò Ọjà l'Ékìtì gbọ̀pá àṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 11, 2021

Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀: Olukere tìlu Odò Ọjà l'Ékìtì gbọ̀pá àṣẹ


Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa tun fitan tuntun balẹ fawọn araalu Odo Ọja, Ikere Ekiti nipinlẹ Ekiti nigba ti Ọba Ganiyu Ọbasọyin gbọpa aṣẹ lọwọ ijọba ipinlẹ naa, Gomina Kayọde Fayẹmi.
 
Ijọba ibilẹ Ikere nilu Odo Ọja, Ikere Ekiti wa, nibẹ si ni Ọba Ọbasọyin ti jẹ Olukere, nibi ti ẹsẹ ko ti gbero.
 
A gbọ pe lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo, idanwo ti awọn igbimọ afọbajẹ nilu naa ṣe fun Ọba Ọbasọyin, lo mu ki wọn mu kabiyesi lọ siwaju ijọba ipinlé naa lati bu ọwọ luu.
 
Nigba to n gbe ọpa aṣẹ le Kabiyesi tuntun naa lọwọ, Gomina Fayẹmi ti igbakeji rẹ, Oloye Bisi Ẹgbẹyẹmi ṣoju fun gba kabiyesi atawọn ọmọ ilu naa lamọran lati wa ni iṣọkan nipa fifọwọsowọpọ fun idagbasoke.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI