Ijọba Kwara yan igbimọ ẹlẹni mẹwaa lori ilọsiwaju otẹẹli Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 29, 2022

Ijọba Kwara yan igbimọ ẹlẹni mẹwaa lori ilọsiwaju otẹẹli Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe igbimọ ẹlẹni mẹwaa dide lori ilọsiwaju ati idagbasoke otẹẹli Kwara, eyi ti wọn tipa laipẹ yii latari awọn iwa magomago to n ṣẹlẹ nibẹ.

A gbọ pe igbimọ naa ni yoo sọ ọna ti ijọba yoo gba lati jẹ ki iṣẹ maa lọ deedee, ki owo si maa wọle fun ijọba loorekoore lai si idaduro kankan.

Wọn ni ọna ti iṣẹ yoo gba bẹrẹ ni otẹẹli Kwara yoo ba ti agbaye mu, nitori pe bi igba ti iṣẹ ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ ni pẹrẹu ni, pẹlu awọn oṣiṣẹ ti wọn ni oye.

Lakoko ti wọn n fi igbimọ naa lelẹ nileeṣẹ ìjọba to n ri sọrọ okoowo ati imọ ayelujara, Ministry of Business, Innovation and Technology, alakoso agba ileeṣẹ naa, to tun jẹ alaga igbimọ ọhun, Ọnarebu Ibrahim Akaje, gba awọn ọmọ igbimọ naa lamọran lati fọwọsowọpọ fun iṣẹ idagbasoke.
 
Awọn ọmọ igbimọ ọhun yooku ni Anthony Gana Abu to jẹ akọwe, Senior Ibrahim Sulyman Esq., Arc. Aliyu Muhammed Saifudeen, Arabinrin Florence Oyeyẹmi Ọlasunbọ, ati Mallam Abdulmajeed Abdullahi.

Awọn yooku ni Ajeje Oluwaṣeyi Bamidele, Alaaji Saadu Salahudeen, Alakoso fidihẹ fun otẹẹli Kwara, Ọgbẹni Salami Moshood ati Oloye Ọmọgbenle Adeyẹmi.

Nigba to n sọrọ, Akaje sọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n fẹ idagbasoke to lọọrin nipa imọ ayelujara, ati pe o n fẹ ki ipinlẹ naa maa lewaju kaakiri agbaye, ko si di ilu t'awọn lagbaye n wa lati dokoowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI