Ọpẹ o! Ijọba Kwara bẹrẹ eto ẹkọ ọfẹ fawọn akẹkọọ ofin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Ọpẹ o! Ijọba Kwara bẹrẹ eto ẹkọ ọfẹ fawọn akẹkọọ ofin


Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ pinpin awọọdu eto ẹkọ ọfẹ fawọn akẹkọọ ti wọn n kẹkọọ nipa imọ ofin nipinlẹ naa.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo awọn akẹkọọ naa ti wọn je ojulowo ọmọ ipinlẹ ọhun ti wọn wa kaakiri orileede Naijiria ni wọn lanfaani si eto ẹkọ ọfẹ yii.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ giga (Tertiary Education), Ọmọwe Alabi Afees Abọlọrẹ lo sọ eyi di mimọ nibi ipade to waye ninu ọfiisi rẹ l'Ọjọru, Wẹsidee ọsẹ yii.

O ni owo eto ẹkọ ọfẹ naa ni wọn yoo san sinu apo owo ile ifowopamọ awọn to ba jẹ anfaani naa lati ṣe otitọ pẹlu rẹ.

Ọmọwe Abọlọrẹ sọ pe eto ẹkọ jẹ gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq logun pupọ, idi ree to fi n karamasiki ọrọ awọn akẹkọọ.

Siwaju sii lo sọ pe awọn yoo gba iwe akọsilẹ orukọ awọn akẹkọọ imọ ofin naa lọdọ awọn alaṣẹ lati mọ bi wọn yoo ṣe san owo naa fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI